Bo tile je pe oro enu lasan ni oga,
osise atawon akekoo ile eko girama Muslim High School to wa lagbegbe Sabo ninu
Sagamu ipinle Ogun koko ro pe gbajumo osere tiata aderin posonu nni, Otunba
Bolaji Amusan topo si Mista Latin, eni to tun je oludasile ajo oniranlowo Mista
Latin Foundation n so nigba to ranse si won pe oun n bo, sugbon ti won ko ri
lasiko to da fun won.
Mista Latin ati Labake |
Gege bi AWIKONKO se gbo, idi ti Mista
Latin se ranse si won ni lati seranwo ati lati fi ebun ta Labake Samson, omodun
mokandinlogun to ri poosi owo he, to si muu lo si banki ti kaadi ti won fi n
gbowo wa ninu eni to ni poosi naa ninu e.
Iyalenu loro omo naa je fun Mista Latin
nigba tiroyin naa te lowo, to si woo pe omo gidi ni Labake Samson je, nitori
eko to gba lati odo awon obi e, paapaa nigba to gbo iru ise ti iya Labake n se
pe ise awon to n gba ile ojo titi lo n se.
Ipo ti iya Labake wa yi lo ta Mista
Latin lara to si woo pe o ye koun fomo naa lebun to joju. AWIKONKO gbo pe
egberun lona ogorun (100,000) naira ni Mista Latin koko fun Labake, to si fi
ebun awoodi gba nidi gege bi omo to ni otito.
Idi ti Mista Latin ko fi lo lojo to
seleri fun won, iyen lojo Isegun Tusde to koja ni ti ipalemo ayeye isinku ti
agba osere tiata nni, Oloogbe Pasito Ajidara nitori pe Mista Latin ganagan ni
won fi se alaga eto isinku naa, ti ko si saaye fun un.
AWIKONKO gbo pe awon eeyan naa ti so
ireti nu pe Mista Latin ko paro fawon ni, sugbon iyalenu lo je fawon eeyan naa
nigba ti won oko Mista Latin Foundation to wonu ogba ile eko naa laaro Ojobo
Tosde to koja yi.
Won fee di Mista Latin mu |
Ariwo Mista Latin ti de lo gba ogba ile
eko naa kan nigba tawon ti won so pe won wa lenu eko lowo fo jade sita lati waa
wo Mista latin nitori pe inu fiimu ti won n wo nikan ni won ti n ri, opo won won
ni ko rii ri ti won si fee wo o.
Idunnu subu lu ayo lojo naa, ti won si
sare kan si iya Labake nibi to wa pe ko tete maa bo, Mista Latin ti de, o si
fee fun Labake lebun gege bo se seleri. Loju ese lobinrin naa ti sare wo aso
nitori pe iro nikan la gbo pe o ro mo aya lakoko ti won pe e.
Ko seni to le so binu awon eeyan se dun
to nigba ti won foju kan gbajumo agba osere aderinposonu naa. Ireti opo awon
eeyan logba ile eko lojo naa ni pe ki Mista Latin sere fawon, tabi kop awon
lerin, sugbon won o mo pe Bolaji Amusan lo wole to won wa, kii se Mista Latin.
“Labake da, nibo lo wa” lariwo ti won
koko n pa a nigba ti won ri Mista Latin, to si gbosuba kare fun un nigba to
foju kan an laaro ojo naa. Loju ese lo ti fun lawoodu ati owo. Kii se owo ati
awoodu nikan la gbo pe Mista Latin fun Labake, o tun seleri fun un pe oun yoo
sagbateru eko Labake digba ti yoo fi jade ile eko giga fasiti.
“E je n baayin ya foto, emi naa fee baa
yin ya foto, emi lo ni foto kan” lariwo tawon oga agba, tisa atawon ile eko naa
n pa lojo naa, sugbon Labake lo gbayi ju lojo naa, to si ba Mista Latin bowo,
to tun di mo.
Mista Latin pelu awon oga ileewe naa |
Nigba to n soro, Mista Latin so pe
“Nnkan tomo naa se je ohun iwuri fun mi ni pe, nigba ti mo gbo isele naa, pelu
ipo tiya omo naa wa ati ise to n se, gege bi eni to n gba ile titi kaakiri,
ko je ki ojukokoro woo loju, to fi mu poosi naa peluu egberun
mejidinlogun naira to wa nibe, to si muu loo si banki dajudaju eko tawon obi e
ko lo gbe jade.
O wa lo akoko naa lati gbawon akekoo
egbe e lamoran pe ki won fi ti Labake se awokose.
AWIKONKO tun rii gbo pe ile eko Muslim
High School naa gba awoodu lowo ajo Mista Latin Foundation fun ti ipa ti won ko
lakoko naa tisele naa waye ati eko ti won fi n ko awon akekoo.
No comments:
Post a Comment