Nitori oro ile, won dana sun Kabiyesi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 31, 2017

Nitori oro ile, won dana sun Kabiyesi

Afaimo ki awon alale ma dide ibinu sawon to sagbateru iku Oba alaye kan nijoba ibile Yewa South, Oba Patrick Oyeniran Fasinu to je Olowo tilu Owo latari bi won se so pe awon kan lo wa nidi isele naa.

Oba Olowo
Bo tile je pe owo olopaa ipinle Ogun ti te Bolaji, to je okan lara awon to seku pa Oba Fasinu, ti won si tun ti mu awako e sahamo lati foro waa lenu wo nitori ti won so pe aso to kangun si eegun lo n je jepe, eni ti won so pe ohun lo ri Kabiyesi gbeyin.

Gege b’AWIKONKO se gbo, ko ju iseju marun un ti won so pe Kabiyesi ja awako e sile, lawon odaran naa da kabiyesi lona lagbegbe abule Ijako-Isagbo ni Oke-Odan, ti won si saa lada titi to fi ku ni nnkan bi aago mewaa ale Ojoru Wesde to koja yii.

Won ni ero okan awon eeyan yi ni pe kabiyesi naa ko le ku tan, o si seese ko ji pada, eyi lo faa ti won so pe won tun dana sun un mo inu moto e lale ojo naa, ki won too na papa bora.

Awon ti won n koja lo lasiko isele naa, ni won so pe won ko le duro lati gba kabiyesi sile, ati pe nise lawon eeyan naa sa asala fun emi won, ki won ma baa da emi ti won naa legbodo, sugbon leyin tawon eeyan naa salo tan la gbo pe awon eeyan bere sii yoju lati mo iru eeyan ti eni ti won dana sun je.

Igba ti won sunmo ibi ajoku moto naa ni won too ri pe Kabiyesi lo wa nibe, lesekese ni won ti bere sii royin iku naa kaakiri ko too di pe awon oloye atawon ebi Kabiyesi gbo.

AWIKONKO gbo pe bi won se gbo ni won ti loo foro naa to awon olopaa leti lati le sewadi awon to wa nidi isele naa, sugbon lojo keji la gbo pe owo awon odo abule te Bolaji, eni ti won loo sonu sinu igbo, to si n wa ona lati lo.

Bo tile je pe won ni se ni Bolaji towo te yi, eni ti won pe ilu Ekoo lo ti tele awon iko e to waa seku pa kabiyesi so pe oun ko mo nnkan kan nipa isele naa, sugbon leyin tiya dun un daadaa lo jewo pe ki won se oun jeje, o leni to ran awon.

Gbogbo oro ti won ni Bolaji so kale niwaju Baale ilu Ogbo, nijoba ibile Ipokia ni won ti mo pe ise agbero lo n se, ati pe awon to ran awon nise naa ti so pe leyin tawon ba pa kabiyesi tan, kawon tun dana sun un patapata.

Ibinu ni won fi mu Bolaji lo si tesan awon olopaa ekun Ipokia ko too di pe won gbe e lo si Ilaro lati tubo loo foro waa lenu siwaju sii. Sugbon ni bayii, AWIKONKO gbo pe Elweran ni Bolaji wa bayii.

Omoba Mathew Olaolu fasinu to je aburo kabiyesi to doloogbe nigba to n b’AWIKONKO soro nipa isele naa je ko di mimo pe lati nnkan bi odun ketala ti kabiyesi ti gbade ni wahala orisirisi ti n sele laarin ilu.

O so pe ojoojumo ni won n gbe kabiyesi lo sile ejo nitori wahala to wa laarin eya Anago ati Ogu, pelu bi won se so pe ijoba ipinle Ogun gba ile won fun dida oko sii, to si je pe igbagbo won ni pe kabiyesi ti gbowo abetele lowo ijoba, eyi ti ko je so ohunkohun lati fi tako ijoba to gbale lowo awon to nii. Bee lo so pe ejo naa si wa ni kootu kan l’Ota.

Okan lara awon oloye nilu naa, Oloye Adetunji Iroko sapejuwe Oba Fasinu gege bi eni ti kii fa wahala, to tun ni iberu Olorun lokan. O nilosiwaju ati idagbasoke ilu naa lo je kabiyesi logun ati pe lojo tisele naa sele, ipade awon oba lo ti n bo.
Agbenuso ileese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe iwadii si n lo lowo lati mu awon odaran naa bale, kawon si le foju won bale ejo. O ni ko sidajo ti olopaa fee se bi ko se pe ki adajo pasee.

Bee lo gbawon araalu lamoran pe ti won ba kefiri awon odaran ladugbo won, ki won tete fi to awon olopaa leti, ki won ma se pinu lati se idajo lowo ara won nitori pe ijiya wa fun awon to ba se bee.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI