Awon nkan ti e o mo nipa Iroyin Awikonko - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 25, 2017

Awon nkan ti e o mo nipa Iroyin Awikonko


Ka dupe lowo eni to ri ni to moju, opo eeyan ni ko wo ibi ti a wa rara, eyi lo ni ibamu pelu bawon to mo riri awon iroyin lede abinibi to n waye latigbadegba, ti won si n gbosuba kare fun awon iroyin wa lati osu kinni odun yi ti a ti bere sii gbe orisirisi iroyin jade ni pereu bo tile je odun 2010 lati wa.

Opo awon eeyan ni won ti bere sii se sadankata fun IROYIN AWIKONKO to je pe ori ayelujara intaneeti nikan lo si wa bayii, ti won si n royin bo se n lo lawujo fawon araalu.

Kii se tenu, akoko iru e ni AWIKONKO je nitori pe ko tii si iroyin lede abinibi to je pe ori ero ayelujara nikan lo wa, ti won si n mu iroyin wa fawon to ti n wa ona lati maa ka iroyin lede abinibi won tii se Yoruba.

E ma je ko ya yin lenu pe bi won se n ka awon iroyin wa lorileede Naijria, bee naa ni won ka a loke okun. Awon orileede bii Canada, Ukraine, United Kingdom, Brazil, Argentina, United States, Afghanistan, Manchester United atawon min in ni won ti n kaa IROYIN AWIKONKO, ti won si n fi ateranse osuba kare fun wa.

Bi won se n kaa lawon orileede ti a daruko wonyii, bee naa lo je pe won tun n ka a nile lawon orileede ile adulawo bii Kenya, Malawi, Ghana, South Africa, Togo, Benin Republic, Saudi Arabia (Dubai) ati bee bee lo.

Bo tile je pe ohun tawon eeyan to n fiwe ranse si wa n so ni pe ki a tubo je ki aami wa lori awon oro ti a n ko, ko le rorun fun won lati ka daadaa, ati pe ka gbiyanju lati maa yan omo sidi awon oro wa, sugbon ti a fi n daa won loju pe igbese ti n lo lori e, laipe igbadun ara oto n bo lona.

E se pupo, bi e se n ka awon iroyin wa. Anfaani wa fun ipolowo oja yin lori IROYIN AWIKONKO lowo ti ko gara rara. E se pupo.

1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI