Oro buruku toun terin; Gomina Fayose gbayii mo Amosun lowo l’Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 25, 2017

Oro buruku toun terin; Gomina Fayose gbayii mo Amosun lowo l’Ogun

Bee l’Amosun fee gbena woju Ajimobi ati Aregbesola
 
Opo awon to wa nibi ipade awon Gomina ile Yoruba, iyen Southwest Governors’ Forum ti won se lojo Aje Monde ana, nigba ti Gomina Amosun gba gomina nla marun un lalejo nilu Abeokuta tii se olu-ilu ipinle ogun loro naa si n ya lenu titi dasiko yi.

Awon to wa nibe lo le royin ohun toju won ri, sugbon tenu won ko le royin tan lojo naa, nitori bi Gomina ipinle Ekiti, Osokomale, Ogbeni Ayodele Fayose se gba okiki ola ati eye to ye ki gomina Amosun to je oun gan an ni olugbalejo awon gomina mefa naa gba nitori aseyori abajade ipade naa, eyi ti won so pe fun alaafia ile Yoruba nipade naa wa fun.

Gege b’AWIKONKO se ri bi gbogbo nkan se lo lojo naa, bo tile je pe awon osise gomina Amosun se ojusaaju, ti won ko je ki gbogbo awon oniroyin wole sinu gbongan ti won ti sepade alakoko won, yato sawon oniroyin kan ti won ti lo ogbon alumokoroyi lati foruko sile nitori ajosepo won pelu awon osise ijoba naa.

Inu ogba MITROS to wa ninu Ibara nipade naa ti waye, eyi to ye ko bere laago mesan an aaro, sugbon to je pe aago mejila koja iseju marun ni won sese bere nitori awon gomina kan to pee de.

Ko too di pe awon gomina bere sii de niporuru okan ti koko ba Gomina Amosun nitori tawon Gomina to n reti ko tete, ki won le bere ipade ti won tori e ya ojo nla naa soto.

Bi Gomina Amosun se n wole, lo n jade, to n fi foonu e pe awon to n reti lati mo ibi ti won de, sugbon bo se n pe lori foonu e, lo dabie pe ipe naa ko ja gaara, eyi lo faa to fi n ranse pe awon osise e, pe ko pe awon dereba atawon to n mu won mona, lati mo ibi ti won de.

Si iyalenu, Gomina ipinle Ondo, Rotimi Akeredolu lo koko de ni nnkan bi aago mewaa koja iseju meloo kan, lesekese ti Gomina ti gbo pe Gomina Akeredolu ti wa ninu ogba MITROS naa, lo ti sare bo sita ninu gbongan to wa, to si sare loo fi erin pade, ko too muu wole lo jokoo.

Bee ni won reti awon Gomina to ku titi, sugbon nigba to maa di nnkan bii aago mewaa ku iseju marundinlogbon lariwo Ambo, iyen Gomina Ambode tipinle Ekoo gbode kan, tawon okada ti won n pe ni Machine Gun marun, ti won fi n sare se atona e wole, ko pe too de ni Amosun ti sare loo pade oun naa lenu ona, to si muu wole lo sibi to maa jokoo sii.

Ko ju iseju meeedogun lo ti Gomina Ambode wole, nibi ti Gomina Amosun ti n ronu kaakiri, to n fi foonu e monito awon alejo to n reti, lo ba wole, bo se wole tan, lariwo ayo so lati iwaju OPIC to wa n’Ibara, tawon eeyan si bere sii pariwo “OSOKOMOLE iwo la n reti, gomina daadaa”.

Lati ‘be la gbo pe awon onilu bere sii filu korin tele Gomina ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose, ti won n kii ni mesan an mewaa titi to fi wonu ogba tipade naa ti fee waye. Bo se fee wole, lo tun duro juwo sawon eeyan to ferin alaafia ati ayo pade e.

Bo tun se wole, to fee ya wo enu ona abawole gbongan, lo tun yi gilaasi jiipu Lexus e wale, to si ki awon eeyan nibi tawon akoroyin lorisiri ti won ko faaye gba lati wole jokoo sii, tawon yen naa si pariwo “OSOKOMOLE”.

Biroyin Gomina Fayose se kan si Gomina Amosun la gbo pe o ti ka kiji nibi to wa, to si sare bo sita lenu ona lati pade e, sugbon awon to ri bi Gomina ipinle Ogun se rerin pade elegbe e yi, ni won mo pe erin iyangi ti ko denu lo fi pade e, bee inu e dun pe o wa.

Opo awon eeyan ni won ti ro pe Gomina Fayose ko nii yoju nibi ipade awon Gomina naa olosu meta-meta naa, nitori to je pe oun nikan ni Gomina to wa lati inu egbe alatako, eni tawon eeyan ro pe ko figba kan gba ti aare orileede yi, Muhammadu Buhari.

Dide ti Gomina Fayose de yi, lo fee bi Gomina Amosun ninu sawon Gomina ipinle meji to je pe irin-ajo won silu Abeokuta ko ju wakati kan si meji lo, iyen Gomina ipinle Oyo ati Gomina ipinle Osun, nitori to rii pe itiju lo fee je pe eni tawon si n se iye meji lori e tun saaju awon ore kori-kosun e de.

Eyi gan an lo fa ti okan Gomina Amosun ko fi bee fi tara-tara bale mo, to je pe iseju-iseju lo n lo, to m bo. Bo se n pe osise kan pe ko bawon mo ibi tawon Gomina meji to ku de, bee lo n pe elomin in lati beere bakan naa.

Leyin bii wakati kan, iyen ni nnkan bi aago mejila ku iseju mejila ni ariwo ilu mi in tun so nita, tiroyin si kan si Gomina Amosun pe Gomina Ajimobi ti wa nitosi lo ti sare pe igbakeji e, Yetunde Onanuga atawon amugbalegbe e kan bii Tolu Odebiyi atawon min in lati pade e.

Gege bi ise awon Oyo, ilu atorin lawon to tele gomina Ajimobi wa lati Oyo fi tele de enu ona kawon olopaa too le won jade, ti Gomina Amosun si mu Gomina Ajimobi wole lati loo fi aga to maa jokoo si han an.

"Nibo le de" la gbo pe Gomina Amosun n beere lowo enikan lori foonu, bo tile je pe AWIKONKO ko sun mon on lati beere, sugbon to ye wa pe Ogbeni ni gomina n beere ibi to de, sugbon si iyalenu, ko ju iseju mewaa ti Gomina Ajimobi wole, ni Gomina Amosun tun sare jade senu ona pelu awon isongbe e lati pade Ogbeni Rauf Aregbesola tipinle Osun.

Bo tile je pe inu e ko fi bee dun lori bawon gomina mejeeji se pee de, sugbon tayo atidunnu la rii pe Amosun fi mu won wole, ti won si sepade won fun bii ogoji iseju ko too di pe won jade lati ya foto, nibi tawon eeyan tun ti raaye gboriyin fun Osokomale tipinle Ekiti, toun naa si fayo dawon lohun.

Gbogbo bi won se n ki Gomina Ayodele Fayose lojo naa ni ko fi bee dun mo Gomina Amosun ninu, nitori to ti ro pe oun gan an lo ye ki won yin, ki won gbosuba fun pe oun loun gbawon eeyan naa lalejo nipinle oun, sugbon oro ko ri bee.

Titi ti won fi pari ipade lojo naa, ti won wo ile ounje lo lati jeun, lawon eeyan si n pariwo “Fayose, Osokomale”, sugbon sibe, Gomina Fayose gan an ni Gomina Amosun n tele, ko le je kawon eeyan mo pe ore timo-timo ni won, awon kan le ma si ninu egbe oselu kan naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI