Won yeye Yinka Adebanjo nibi idibo TAMPAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 26, 2017

Won yeye Yinka Adebanjo nibi idibo TAMPAN

Beeyan ba wa nibi ti won ti le Alaaja Olayinka Adebanjo, eni to je Welfare officer egbe osere tiata TAMPAN, eka tipinle Ogun danu nibi eto idibo egbe won to waye lojo Isegun Tusde to koja yi, yoo ro pe obinrin naa wa ninu egbe alatako ni.

Gege b’AWIKONKO se rii gbo, aago mewaa aaro ni won ni won ti pinu lati bere eto idibo naa tawon omo atawon oloye egbe ti fenu ko si nitori awon to n bo lati ona to jin bii Ijebu, Odeda, Ifo, Yewa ati beebeelo.

Sugbon nitori aago ile Afrika (African Time) to ti mo wa lara ni won tun se fi oore ofe wakati meji sile, ti won si sun eto idibo siwaju pe to ba di aago mejila lawon yoo too bere nitori ti won tubo n duro de awon omo egbe min in to n bo lona.

AWIKONKO gbo pe b’aago mejila se lu ni Alaaji Lateef Lolade Deinde, eni to je okan lara awon igbimo to duro gege bii INEC to sagbateru eto idibo naa bere sii pe awon omo egbe na pe ki won maa wole leyo kookan, to si bere sii pe oruko awon to ye lati dibo.

Bawon eeyan naa se wole tan, ti won jokoo, ni Omoba Bolaji Amusan, Mista Latin to je alaga eto idibo naa gbawon eeyan naa lamoran pe ki won rii daju pe won je keto idibo naa waye bo se ye ko waye, ki won ma se ojusaaju enikeni, ki won si fi iwa omuluabi han. O tun salaye fun won nipa bi won yoo se dibo.

Bo se di aago kan kuseju meedogun ti won bere eto idibo naa ni pereu, tawon oludibo si bere sii dide lati loo dibo won bo se ye. Ko ju bii iseju meta ki won dibo tan, ni Alaaja Yinka Adebanjo silekun wole, bi won se rii pe oun ni, lawon omo egbe naa ba pariwo pe ko bo sita, nitori to pee de.

Obinrin naa koko fee lo owo agbara, gege bi ipo e sugbon ariwo tawon omo egbe naa pariwo pe ko jade sita, ti Mista Latin naa tun fi awada so pe ko bowo fun ofin egbe, ko fi towotowo ba won pada sita nibi to ti n bo.

A fi bi eni pe won ti n wa obinrin naa de tele lori lojo naa nitori ti won so pe itiju lobinrin naa fi bo sita, to si loo jokoo sori aga to wa lenu ona pelu ironu itiju to gba latodo awon omo egbe naa.

Won ni gbogbo ero okan e bo se n bo lojo naa ni pe ko si nkan ti won fee se, nitori pe oloye egbe loun, sugbon to ti gbagbe pe ko seni to koja ofin.

AWIKONKO gbo pe inu ironu ni Alaaja Yinka Adebanjo wa titi ti won fi pari eto idibo lojo naa, sugbon toju e koro bo se rii pe awon eeyan ti n jade, ti ko si si nnkan to fee se sii.

Nigba ti won maa beere lowo e pe ki lo fa toun naa fi pee de, nnkan to so ni pe soosi toun maa n lo ni gbogbo ojo Isegun Tusde loun ti n bo, nitori pe oro oun n fe adura, oun ko si gbodo foro aye oun sere.

Ninu iwadii l’AWIKONKO ti gbo pe adura aago mewaa aaro si aago meji osan to maa n waye ninu ijo kan taa foruko bo lasiri to wa ladugbo Leme, Ewang lobinrin naa ti n bo lojo naa.

O loun ko mo pe oun maa pe to bee, ati pe eto adura naa ko see sare kuro lai pari e, lo je koun duro, sugbon toun ko ti e tun duro bawon se oore ofe, nitori ileri toun ti se lakoko ipalemo idibo. Bee lo rawo ebe sawon omo egbe pe ki won foriji oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI