Mi o le gbagbe ojo tawon ole gba oruka igbeyawo lowo mi leyin ose kan ti mo segbeyawo - Tantala - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 26, 2017

Mi o le gbagbe ojo tawon ole gba oruka igbeyawo lowo mi leyin ose kan ti mo segbeyawo - Tantala

* Mo lo s’Ekoo, mi o rowo moto pada s’Abeokuta
* Mo ti n lo moto saaju Awolowo, sugbon awon eeyan bi esu lo daarin wa ru

Bi a ba n so nipa awon to mo ede e pe, ti won fi n pe won ni pedepede; bi a ba n daruko awon toro da saka lenu won, ti won fi n pe won ni sorosoro; bi a ba wa n so nipa awon ti ise sorosoro ye daadaa, odu ni Oloye Michael Sunday Ogunsola tawon eeyan mo si Tantala je, kii saimo foloko. Okunrin naa so awon ojo ti ko le gbagbe nidi ise to yan laayo yi, paapaa nipa awon ipenija lorisiri to ba pade. Nigba to b’AWIKONKO soro laipe yii, o ranti awon iya to ti je ki Olorun to gba fun un. Eyi ni bi iforowero naa se lo.

AWIKONKO: E ku ojo meta, oruko yin lekunrere?
TANTALA: Oruko mi o yi pada, Oloye Michael Sunday Ogunsola tawon eeyan maa n pe ni ‘Tantala lori okada".

Tantala
AWIKONKO: Opo awon eeyan ni ko fi bee mo oruko yin, nibo ni inagije yin “Tantala” ti jade
TANTALA: Ope ni fun Olorun, o ti to bi odun meloo kan seyin peluu Oloogbe Omoba Gbenga Adeboye la jo wa nigba yen. A jo kuro nilee itura Gateway lodun naa lohun, won fee lo seto lori redio OGBC, emi ni mo wa moto won lojo yen. O ni omobinrin kan to n je Lara lo wa lati ilu Ibadan, to wa se IT nileese OGBC. Bo se ri mi lojo yen lo so pe ‘e wo bi bobo yi se gbe sa. E wo bo se ri tantala’, bi mo se woo mo lowo ni yen, ti inu si bi mi gan lojo yen, ti mo so fun un pe laye e, ko ma pe mi ni oruko buruku. Nnkan to faa nigba yen ni pe mo gbe, mi o sanra. Nibi ti a ti n fa oro naa ni Oloogbe Gbenga Adeboye ti ba wa nibe, to si beere pe ki loo sele, ki n too salaye fun un, sugbon iyalenu lo je nigba toun naa so pe ‘oruko too si maa je niyen’.
Ko si lori okada ninu oruko yi nigba yen, igba ti mo bere eto ti a pe ni “O le ku on Teli” lori amohunmaworan, telifisan OGTV pelu Alaaji Asamu Akinrinde. Laarin eto naa la ti ya abala kan soto lati lo maa fi beere ibeere apanilerin lowo awon araalu, okada ni mo maa n ya lo lati fi beere awon ibeere naa, eyi lo faa to fi di ‘Tantala lori okada’.

AWIKONKO: Oto ni ise tawon eeyan mo yin mo latile, bawo gan an le ti e se bere ise yii?
TANTALA: Looto ni, mo ti koko sise ina iyen electrician ri. Mo ti ba onifidio mu ina dani lode ariya ri. Igba ti mo rii pe owo wa lori e, lemi naa tun lo koo. Pelu oore ofe Olorun, mo ra kamera meta, ti mo si si ofiisi ti mo pe ni Jesus Power Film Production. Mo tun se fiimu kan jade, ti Odunlade Adekola n ba wa ko waya kaakiri. Nibe ni mo ti mo awon eeyan bii Omodo Agba. Leyin yen ni mo tun loo ba Oloye Asamu Akinrinde to ko mi nise sorosoro lodun 1997. A jo bere egbe FIBAN ni nitori pe lojo ti won maa da sile, mo lore ofe lati wa nibe. Okunrin kan, Kola Olootu lo se asemase n’Ibadan, ti won so pe o bu Obesere, iyen lo fa ti won fi le danu. O wa ba Oloogbe Gbenga Adeboye ni Oteeli Gateway nigba yen pe se ni won le oun danu nitori toun bu Obesere. Ibe ni won ti ronu pe kani awon ni egbe ni, iya naa ko ni je nitori pe egbe lo maa dide iranlowo. Lesekese ni Gbenga Adeboye ti so fun un pe ko wa maa ba oun seto, lo ba fun un ni wakati kan ninu wakati meji to n lo nileese OGBC nigba yen. “Akanji Olowo Eje” ni itan ti Kola Olootu n se nigba yen.

AWIKONKO: Opo awon eeyan ro pe oloogbe Gbenga Adeboye ni oga yin, sugbon e so pe Asamu Akinrinde ni. E tubo tan imole sii.
TANTALA: E se e, looto ni. Gbogbo won ni oga mi, sugbon nitori Asamu Akinrinde sise nileese JYO Records nipinle Ekoo nigba yen. Ko saaye fun won lati maa wa ipolowo kaakiri, ohun lo faa ti mo fi n ba won wa ipolowo lati maa lo lori eto taa n se nileese OGBC. Ibe gan an ni mo ti pade Oloogbe Gbenga Adeboye ati Oloogbe Toba Opaleye, ti a si wonu ara wa. Nibi ti a wonu ara wa de, iyawo ile Toba Opaleye, emi ni mo ko won bi won se n wa moto. Nipase Toba Opaleye ni mo fi mo Gbenga Adeboye nitori pe adugbo kan naa lemi ati Toba Opaleye n gbe l’Okejigbo nigba naa.

AWIKONKO: Awon eto ori redio wo le fi bere nigba yen?
TANTALA: Ope f’Olorun lonii, nitori pe ise teeyan ba n se, ti ko ba mon on daadaa, to ba tubo tera mo, to ba ya, o maa yege nibe. Bee gele loro mi. Oore ofe ni mo ri gba lowo Olorun. Nigba ti mo maa koko bere lori redio OGBC, AM ni mo ti bere, Oloogbe Semiu Kareem lo fun lakoko ti mo n lo nigba yen, Eto akoko naa ni mo pe ni “E soko ijo” lojo Satide Abameta, igba to ya, ti won ri bi eto naa se n mi igboro, ni won tun fun mi ni eto min in ti a pe ni “E ku iyaleta” lojo Wesde. Bi Oloogbe Gbenga Adeboye ba se n seto ni FM, akoko na lemi n se ni AM, tawon eeyan si n gbo wa papo. Igba ti wahala naa po, ni mo fa eto ojo Satide yen le Idowu Taiwo lowo, nitori o maa n wa jokoo pelu mi. igba to ya ni Alaaji Kola Poloola naa tun darapo mo mi lori eto “E ku iyaleta”.

AWIKONKO: Ko si ise ti ko ni adojuko ninu paapaa nidi ise yi, ki lawon ipenija ti e le so pe e ba pade, paapaa nigba ti e bere?
TANTALA: Ipenija po, bii ka lo si Idumota lati loo wa ipolowo ati maketa lo. Ojo kan ni mo wa eeyan kan lo s’Ekoo lati gba ipolowo lowo e, sugbon ti mi o ba lojo naa. Ibanuje lo je fun mi nitori pe mi o lowo moto lati fi pada siluu Abeokuta ti mo ti wa. Owo lo ni ki n wa gba, sugbon nigba ti mo maa d’Ekoo, o ti pa foonu e, mo pe e titi, ko lo. Awon ti mo tun mo pe won sunmo on, ti mo tun loo ba, won tun so pe mi o le rii, a fi ti n ba pee. Opelope maketa kan to gbe lo sile e ti mo loo sun. Mi o le gbagbe ojo ti a lo jo ijo Barrister pelu Asamu Akinrinde, nigba ti a n pada bo lawon ole da wa lona, ti won ju taya si ese moto wa. Ose kan leyin ti segbeyawo ni, won gba oruka igbeyawo lowo mi, aago owo mi ati owo mi pelu ti Asamu Akinrinde, sugbon ope ni f’Olorun tori pe dukia ni won gba, won o gba emi wa.

AWIKONKO: Opo awon eeyan lo mo pe Olumide Awolowo le jo n seto tele, ti e n se bii ibeji, sugbon oro naa ko ri bee mo bayii, ki lo faa?
TANTALA: Beeni, e se gan an. Mo ti n da seto ki n too pade Olumide Awolowo rara. Okan lara awon oloye niluu Elite, Oloye Samsondeen Somuyiwa lo fi oro Olumide lo mi pe oun naa moro o so, bi a se pade niyen, to fi darapo mo mi lori eto ti mo n se. Ise yi, beeyan ko ba sora, eni to ba n baayan seto papo, ti ko ba tete year lati da duro, o see see ko ma le da seto mo to ba ya, to je pe bi ko ba ri eeyan lati ba seto, o maa fee nira. Igba to ya ti mo tun loo gba eto lori telifisan NTA to wa ni Ogbe, ni mo tun mu mora pe ko je ka jo maa se e, ibe la ti bere pelu 12and13. Mo ti n lo moto, toun ko tii lanfaani lati lo, mo ti gbe igbe flat, toun ko ti maa gbe, sugbon to ri mi gege bi oga nigba yen. Awon ota bi ore lo ya wa, nitori awon eeyan bi esu lo loo so fun un pe mo n ree je ni. Orisirisi oro ni won so nigba yen, toun naa ko tete ronu pe won fe daarin wa ru, toun naa si ti tomode boo to je pe ojo ti a ba ni eto paapaa lori redio Paramount lo maa n so pe oun ko ni le ri aaye tori oun fee rin irin ajo lo sadura lori oke kan. Lakoko o loun n maa lo ose meji, igba o pe lo tun so pe oun tun n lo sibo min in, bee lo se tosu kan fi pe, igba to su mi ni ni mo so fun un pe to ba pe osu meta, mi o ni gba laaye mo. Eni kan tun fun wa ni yara igbohunsile, studio lagbegbe Iyana-Mortuari nigba naa, mo tun yonda e fun un pe ko maa loo lati fi se ofiisi, nitori pe emi naa ni ofiisi temi ti mo n lo tele. Igba to ya, to pe, lo ba tun pada waa, mo wa so fun un pe ko maa lo, nitori nnkan ti won n so fun un nigba yen pe irawo e ni mo n lo, oun lo n gbe mi. mo ni ko maa lo pelu irawo e, ki n maa lo irawo temi lo lati mo iwon ti mo gbe. O saa bere sii soro naa fawon eeyan, ti won si bere sii pe mi lorisirisi. Igba to ya ni mo pe ipade pelu e atawon kan to n pe mi lori e, ti mo si soo nibe pe mo ti fun lowo pe ko loo gba ile flat ri, se o so fun won, o loun ko so. Mo beere lowo e talo n ko owo dani, o loun ni, a jo n pin owo taa ba pa ni, oun gan an lo maa n yo temi fun mi. o si be mi, mo ni mo ti dariji, sugbon latigba yen la o ti jo seto mo.

Tantala lori Okada
AWIKONKO: Bawo ni ise sorosoro se ri nigba ti e bere ati bo se ri lasiko yii?
TANTALA: Nigba kan, awa pedepede maa n sa fun ara wa ni, tawon kan maa sa foogun pe ki won ma lo foogun gba awon. Ko si ife to jinle nigba naa, a o nife ara wa denu. Sugbon ni bayii, oro naa ti yato nitori pe oju orun to eye e fo lai fapa kan ara won. Ti e ba woo, nileese redio ti mo je okan lara awon oga nibe lonii, Alaaji Moruph Omodo Agba, won ti n saaju mi soro lori redio, to tun je pe mo maa n ran won lowo lati fi moto mi gbe won loo sise irinkerindo won, ti mo maa n ya won ni kamera mi. Ori mi tun maa n wu ti won ba koja niwaju ofiisi mi, ti won pe mi. Lonii, emi tun je gege bi oga fun won, ti won je igbakeji olootu eto nileese redio taa wa yi, kii se tigberaga nitori oga mi ni won je lojokojo, sugbon o ni bi Olorun se maa n sise e.

AWIKONKO: Iyato wo lo wa laarin sorosoro ati pedepede nitori pe sorosoro lawon eeyan mo ju?
TANTALA: Olorun ma je ka soro saa. Oro ni nnkan ti gbogbo eeyan n so. Awon ede kan wa ti a maa n pe lori afefe, to fi je ko yato si oro siso, awon to mon on mo. Ka soro, ka yo ko moo kun jade, ise ti wa ni, ohun ni won fi n pe wa ni pedepede.

AWIKONKO: Nje e ti e ti fojo kan roo pe e si maa fi ise yi sile lojo kan, lati ya sidi ise min in?
TANTALA: Mi o roo ri nitori pe ise ti mo feran ni. Nibi ti mo feran ise yi de, lojo ikomo akobi mi, mo fi ikomo naa sile laaro lati loo ba Asamu Akinrinde loo seto n’Ibadan. Aago meji osan la sese se ikomo to ye ka ti bere lati aago mewaa aaro. Mi o le fi ise yi sile.

AWIKONKO: Ki lo fa ti won o fi je ki e je okan lara awon oga nileese redio Sweet FM to je pe eyin gan an nigi leyin ogba to je kileese redio naa fese mule daadaa, ati pe ki lo de ti won ko se fun un yin leto nibe?
TANTALA: Se e ri ileese redio Sweet FM, emi nikan ni mo se koo kari e, to je pe odindi osu mefa gbako ni mo fi da seto ayewo, ti a mo si transmitting test lati aaro di ale, paapaa mojumo, to si ti mi ilu titiiti, tawon araalu ti feran e gan. Igba yen a so fun oludasile e, iyen Senato Obadara pe ki won je ka je ki ede Yoruba po ju ede Oyinbo lo, sugbon awon igbimo isakoso ti won yan nigba naa so pe ko le ri bee nitori pe ajensi (agency) lawon n wo, tawon si fee fi pawo wole, won ni ko le sise. Igba yen gan an ni won tun ti fi mo egbe pedepede wa. Emi gan an ni mo ko awon omo egbe lo, to fi mo alaga wa nigba yen, Akinyemi Olatoye. Igba to ya ni won pe mi pe se maa gba lati je okan lara awon osise, mo ni rara ko le seese nitori awon ise min in ti mo tun n se. Senato Obadara wa je ko ye mi pe wakati meji gbako lawon fee fun ede Yoruba lojumo laarin ago marun in si meje irole laarin ose kan, iyen Monde si Fraide. Leyin yen ni mo wa loo pe Alawiye to je alaga wa nigba yen pe ko wa a ba Senato Obadara lati mo iru eto ti won fee se nitori pe won fee fun egbe sorosoro wakati meji. Mo je ko ye won pe emi fee gba akoko temi loto ni gege bi ipin temi loto, ni won fi waa fun mi ni aago meta si merin irole ojo Fraide. Igba to ya, lawon kan tun waa pe mi pe won tun fee da ileese redio min in sile, ni oludasile ileese redio naa waa ba mi pe awon ki n maa bo. Mo so fun won pe nigba ti omo won wa nibe, ki won je ko maa se, sugbon won ni emi ni won fe, mo waa so fun won pe nnkan ti mo le se ni pe ki n ran an lowo. Sugbon nigba ti wahala naa po nigba yen, mo ni lati fi ileese Sweet FM sile, nitori pe ko saaye mo fun mi mo, ati pe se ni mo n san owo fi seto nibe. Ohun lo je ki n ronu pe mi o nilo lati lo maa san owo seto mo, nigba ti won ti fun mi ni eto ofe nileese redio Family. Leyin yen, Senato Obadara pe mi pe ko wun awon ki won fi mi sile, mo ni to ba je pe ofe ni won fun mi leto nibe, mo le duro, sugbon mi o le maa san owo fi seto nileese redio ti mo jiya fun. Won ni ki n mu ojo kan lori eto “Ayekooto”, sugbon mo rii pe ko le temilorun pelu awon ti mo n ba polowo oja, ti mo si so pe ko le seese fun mi. Ti m ba si de be lola pe mo fee gba akoko, won a gba mi.

AWIKONKO: Eto kan wa ti e n se laaro Sande lati maa fi ran awon eeyan lowo. Ki lo bi eto yyen gan, ati pe nje e n ro lokan lati da ajo alaanu sile?
TANTALA: Mi o ni lokan lati da ajo alaanu sile. iyalenu ni ipele ti eto naa wa lonii si n je fun mi, nitori pe mi o ti e ni lokan lati maa fi eto naa ran awon eeyan lowo, kayeefi ni. Nkan to faa ni pe, nigba ti a bere redio molebi ti a mo si Family FM, akoko si sile repete. Mo kan woo pe laaro Sande yen, kaka ki won kan maa lo orin lasan, ki won je ki n maa fi sere, dawon eeyan laraya, iyen ti ko ba lo si soosi. Tawon eeyan ba pe mi, mo maa fun won lebun lati apo ara mi, kinu awon eeyan tun le maa fi dun sii. Lojo kan leyin ti mo pari eto, ti mo dele lowo ale, ni arabinrin kan pe mi, to si salaye fun mi pe oun sese bimo ni, ko si si nnkan toun fee je ati omo oun. O loun rii pe mo maa fawon eeyan lebun ati owo, pe ki n ran oun lowo. O ni to ba je iresi kongo kan, ki n foun, nibe ni ara ti ta mi, inu mi baje pelu ipo to wa yen. Ibi to ti n soro naa ni foonu e ti ku. Lati ojo naa titi di ojo ti mo tun fi pada loo seto yen ni foonu arabinrin yen ko lo mo. Ori eto na ni mo ti waa salaye fawon araalu pe eni kan pe mi, o si so isoro to ni fun mi, sugbon foonu ko lo, ati pe to ba n gbo eto naa, ko waa ba mi ki n too pari eto lojo naa. Boro naa se yi mo mi lowo niyii, tawon eeyan waa bere sii lo anfaani e lati maa pe, ti won n so isoro ti won ni. Aya emi gan an koko ja pe iru kini mo ko ara mi si yii. Awon alaboyun, alaisan, awon tebi n pa atawon ti won nisoro lorisirisi si n pe lati so isoro won.

AWIKONKO: Ki wa lawon ipenija ti e n ba pade lori e, nitori pe kii se nkan ti e lero tele ni. Bawo lawon araalu eleyinju aanu se tewo gba sii?
TANTALA: Annu lemi naa ri gba lowo Olorun fun ipo ti mo wa lonii. Ipenija po lorisirisi, bii kelomin in pe wa pe oun fee wa fun wa lowo tabi ni ounje, ko di ojo to seleri pe oun maa wa, ka ma ri. Ti a ba pe e pada lati beere, o le ma gbe foonu e mo. Elomin in le so pe oun ko ri aaye ni. Elomin in gan nitori pe o fee polowo ileese e, o le so pe oun fee fi egberun kan naira seranlowo loruko ileese oun yen, ka ba oun daruko ileese yen pelu nnkan ti won n se nibe, ti a o ba daruko e, se lo maa dabi eni pe a lu oun ni jibiti, eyi ti ofin redio ko si gba wa laaye bee. Opo awon eeyan lo ti so pe ka fun un yan ni eedegbeta (N500) naira, ka si ba oun daruko e ati ileese oun. Ti a o ba si sora se, ileese redio le ro pe a ti gba owo nla, ogbon la ma fi n se e, ti a o ba tun daruko ileese onitohun, yoo tun pe wa labe aso pe ao daruko ileese naa daadaa, ti won o mo bo se lo. Won ti e maa n ro pe a fi n dokowo ni, pe awa naa n ri ti wa nibe, ko ri bee. Mo maa n pe adabi le ara mi lori eto naa pe ti m ba yo ninu awon nkan ti won n fun mi lati fun awon alaini nitori pe ise ti mo n se to mii jeun, to tun too bo awon ebi mi. Eru maa n ba mi lati na owo tto ba di ojo Satide ni, nitori awon to maa pe awon nilo iranlowo lojo Sande ti m ba n seto lowo. Lapo ara mi lojo Sande, ojo ti mi o ba seranlowo rara, ni mo maa n na egberun lona ogun (N20,000) naira. Aimoye awon alaini to ti wa sori eto naa, ti won si lo sile pelu ogberun lona ogun ati egberun lona ogbon naira, kolonka ni won. mo mo pe eni to ba n saanu naa a ri aanu gba, nitori pe ko seni to ba Olorun dowo po to padanu ri. Aipe yi lawon kan sese darapo lati maa fun wa ni ahon eran lati fi seranlowo, bee naa lenikan tun so pe iye toun baa n ni lojo mejo-mejo, oun a maa fi ran wa lowo. Opo awon eeyan ni mo ti ran lowo, ti mi o kii soo lori afefe. Lojo Itunu aawe to koja yi, mi o le ka iye adie ti mo ra lati fun awon eeyan.

AWIKONKO: Ki ni amoran yin fawon araalu paapaa ijoba lati sagbateru eto yin yii?
TANTALA: Iyen gan an nise. Mo ti soo ri lori eto naa pe to ba je pe se la bu ijoba lori eto naa, laarin iseju marun un, won a ni ki won wa gbe wa, sugbon ti a ba ni ki won ran wa lowo, ibe ni a o ti ni gbo nkankan. Ijoba o tii gbo wa bayii, sugbon o di ojo ti won ba bu won. nnkan ti mo mo ni pe oke lowo afunni n gbe. Mo je eeyan kan to ko awon eeyan mora, oun gan an lo fa ti mi o fi n toro owo. Ibunkun Olorun nii mu nii la lai fi laalaa kun. O dara ti a ba ri eni ran wa lowo, tori pe mo mo pe opo awon eeyan ni won ko ri ounje je, emi naa si ti wa nipo naa ri, ti mo si mo bo se n rii. Adura mi ni pe ki Olorun ma fi okuta ropo mi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI