Won niku Abu Olododo kii soju lasan; Aisan eje riru lo paa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 31, 2017

Won niku Abu Olododo kii soju lasan; Aisan eje riru lo paa

Beeyan ba je ori ahun, to ba de ibi ti won ti sinku okan pataki lara awon osere tiata nipinle Ogun, Oloogbe Isaiah Olurotimi Ayinde topo mo si Abu Olododo to ku leni odun mokanlelaadota lojo Aje Monde ose to koja yi, yoo banuje pupo.

Abu Olododo
Bo tile je pe irole ojo tokunrin naa ku ni won ti sin in nilana igbagbo, nitori ti won so pe ko si owo nile ti won le fi gboku e lo si motuari fun ojo pipe, sugbon orisirisi lawon eeyan n so nipa nnkan to sokunfa iku agba osere naa, eni ti won so pe nise lo foro leran ku.

AWIKONKO gbo pe kayeefi niku agba osere omo egbe TAMPAN naa si n je fawon eeyan to sunmo paapaa awon osere tiata, nitori ti won so pe ko figba so pe oun n saisan, eni ti won loo si tun bawon eeyan dapara titi di nkan ti aago mewa n loo lu lale ojo Sannde to ku.

Ori aga to jokoo si ninu yara e lo wa nibi ti won lo n kowe kan lowo ti won ba niwaju e, nile to wa ladugbo Olorunsogo nilu Abeokuta, ibee naa ni won tun sin in sii.

Bo tile je pe oloogbe naa kii fi bee ko pa ninu fiimu, eyi ti ko je kawon eeyan fi bee mo, sugbon to je pe awon gbajumo osere tiata Yoruba paapaa nipinle Ogun ko le fi sere nitori pe agba akowe iranti (continuity director)  ati asatunto ere (screenplay writer) ni.

Nibi isinku naa
AWIKONKO gbo pe aisan eje riru to wa lara Abu Olododo ti le ni odun meta, sugbon ti ko so fenikeni, won ni kii jina sileewosan fun ayewo, ati pe bawon eeyan se sunmo on to, to fi mo aburo e, Abayomi to tun sunmo on ko mo iru aisan naa.

Alaaji Waheed Ijaduade tawon eeyan tun mo si Dimeji, eni to je kawon eeyan gboroyin iku e so f’Alariya Oodua lojo Isegun Tusde pe oun ati oloogbe naa si soro si nnkan bi aago mewaa kuseju mokandinlogun (9:41pm) lale ojo Sande ni.

Ninu oro e, o ni “O ti le ni ogbon odun ti mo ti mo on. Mo lo fun Creative Nigerian Summit kan niluu Ekoo, eyi tijoba apapo sagbekale e, o seni laanu pe ko raaye lo, sugbon se lo n bi mi leere nnkan ti a ba bo nibe, nitori pe iru awon nnkan bee lo maa n nife si nipa ilosiwaju paapaa to ba je mo tise tiata ati lagbo osere.

Lakoko isinku
“Leyin yen, o tun ni awon ise kan to fee se pelu ileese OGTV, temi naa si n gbadura pe ki ero yen ma ku sona bi eefin, nitori pe o ti file sasobora. O n beere nipa awon omo wa to maa nife lati darapo mo ise yen. Mo ni taa ba rira, aa tubo soro sii nitori pe o n fe mo nkan ti mo ri sii, ati iha ti mo ko sii, mi o fe maa so gbogbo lori foonu. Mo si ri ateranse e titi di aago mewaa kuseju mokandinlogun (9:41pm) ale ojo naa lori Whatsapp mi.”

Ohun taa gbo ni pe odun meji seyin ni oloogbe naa padanu iya e to je oludasile ijo kerubu ati serafu nilu Abeokuta. Bo tile je pe iyawo meji ni oloogbe naa fe, sugbon iyawo kan soso la gbo pe o wa lodo e titi to fi ku, to si je pe omo merin lo fi sile lo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI