Awon Ijebu so pe Akinlade lawon fe gege bi gomina ipinle Ogun lodun 2019 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 29, 2017

Awon Ijebu so pe Akinlade lawon fe gege bi gomina ipinle Ogun lodun 2019

Egbe oselu All Progressives Congress, APC eka ti Ijebu Igbo ti so lana ojo Aje Monde pe adije tawon fee sagbateru e gege bi gomina ipinle Ogun lodun 2019 ko pe meji, bi ko se Onarebu AbdulKabir Adekunle Akinlade. 

Asiri yi ni won tu aso loju e nibi abewo tawon agbaagba atomo egbe oselu APC se lo siluu Ijebu lati fokunrin naa han fun won pe oun gan an lo kaju e lati se e. 

Dokita Oshinowo to je okan lara awon agbaagba nile Ijebu, ipinle naa lo soro yi jade nibi ipade naa to waye ladugbo Balogun, ninu Housing to wa ni Ibeba, pe Onarebu Kunle Akinlade lawon fokan tan lati se e. 

Oshinowo so pe gbogbo ile Ijebu to fi mo Remo ko ni nnkan meji tawon tun lee se bi ko se pe kawon gbaruku ti adije to ba wa lati Ogun West nitori pe awon nipo Gomina naa to si.

Agba oloselu naa so pe niwon igba ti Gomina ipinle Ogun, Asofin Agba Ibikunle Amosun ti so pe oun setan lati fowosowopo adije lati ekun Ogun West, toun yoo si gbe ijoba sile feni naa, idi niyii tawon naa ko fi gbodo tun maa da ara won laamu mo.

Be o ba gbagbe loooto, Gomina Amosun so ni nnkan bi osu meji seyin pe adije to ba wa lati Yewa/Awori loun yoo tele, nitori naa kawon eeyan naa lo forikori lati fa eeyan kan kale, sugbon toun ko nii gba adije Tekobo laaye, to ba je pe oun ni won fa kale.

Siwaju sii ni Dokita Oshinowo tun so pe inu oun dun bo se je pe odo ni Onarebu Akinlade, to si je pe awon odo lawon fee ko gbajoba orileede Naijiria.

Bee lo so pe ipo ti oro oselu wa lonii se oun laanu pupo nitori pe o ti yato patapata sigba toun bere pelu awon agba oselu bii Baba Awolowo, Baba Onabanjo ati Baba Obasanjo.

O tun so pe bo tile je pe Onarebu Akinlade ko tii so awon erongba ni rere fun ipinle Ogun fawon, sugbon toun nigbagbo ninu e pe eni to see fokan tan ni, tawon si le fowo e soya.

O wa fi kun oro e pe awon omo Ijebu ko fe ki akitiyan ati igbiyanju awon akoni wa to ti re koja lo ja si asan, nitori pe latile lawon omo bibi ipinle Ogun ti n fe kawon Egbado gbajoba, sugbon ni bayii, asiko naa ti to.

Bakan naa nigba toun naa n soro, Senato Dipo Ogunjimi gboriyin fun akitiyan ati igboya ti Onarebu Kunle Akimlade ni lati jade farahan pe oun nife sii lati dupo gomina ipinle Ogun lodun 2019.

O so pe inu oun dun bo se je pe okan lara awon lara awon akekoo ileewe to dara julo lagbaye, iyen ileewe giga Harvard ti USA, to tun je okan pataki lara awon egbe akekoo, iyen Alumni lo n bo lati di gomina ipinle oun lodun 2019.

Nigba toun naa kadi oro e pelu adura pe Olorun a ran an lowo ninu oro oselu lorileede yi, O ni ko maa ranti nigbagbo pe ipinle Ogun se pataki pupo laarin gbogbo awon ipinle to wa ni Naijiria.

Onarebu Akinlade nigba to n dupe lowo awon agbaagba egbe oselu naa, paapaa awon omo bibi Ijebu fun bi won se gba oun laaye nibi ipade naa, ti wom si tun fi oun lokan bale, o loun ko nii jora oun loju.

Ninu oro e, o so pe "Mo wa si ekun Ogun East lati wa ojurere ati adura yin nitori pe emi naa fee jade gege bi adije lati dupo ipimle yi lodun 2019.

"O da mi loju pe mo kaju osuwon, mo si le se e. Mo ti ba gomina sise papo, mo si ti ko opolopo eko lara e, nitori e ni mo se mo pe mo kaju e lati se e. Mo fee fi kun oro mi pe mo je eni to beru Olorun pupo, mo si je eni to se e fokan tan."

O so siwaju pe awon ipa, akitiyan ati idagbasoke ti gomina Amosun ti se sile, eni to ba niberu Olorun pelu igbiya lo ye ko tesiwaju e, nitori bi ko ba ri bee, Olorun ma je ki gbogbo e pada baje, kii se fun emi, bi ko se ipe lati tun ilu eni se e.

Akinlade lakotan wa muu dawon agbaagba egbe naa loju pe oun ko nii sooju saaju enikeni ninu won, ipo ati aaye tonikaluku ba to si loun maa fi won si, toun ko si nii foju won gbole nitori pe oun mo ipo ti egbe oselu naa wa bayii, ati ibi to ye ko wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI