Ojogbon Adeshina
Sikiru Salami to je oludasile ajo Centre for Yoruba Traditional Culture ti so
pe esin igbagbo (Christianity) lo yi esu tawon Yoruba nigbagbo ninu e pada si
eyi to wa ninu bibeli ati Kuraani. O ni esu to wa ninu bibeli tawon elesin
igbagbo n so nipa yato si esu tawon elesin abalaye nigbagbo e.
Ojogbon King |
O ni bawon Yoruba se
laju to, o seni laanu pee sin igbagbo ti won gbe waa ka won mole losan gangan
lo yi igbagbo won pada, ti won pa esin ati asa won ti segbe kan, ti ko je ki
won nigbagbo ninu e mo bi won se ba a laye.
Ninu oro e, o so pe “Nigba
ti mo pari iwe giga, ti mo pada wa sile lodun 1985, ti mi o rikan sekan, lo je
ki n pada lati loo kawe sii, ti mo si kekoo gboye Ojogbon. Fasiti Sampoulo ni
mo lo, nibi ti mo ti kekoo nipa Management, BsC. Mo tun tesiwaju lati kekoo
ipele keji Masters, ki n too kekoo gboye PhD, to si je pe Yoruba ti mo mu
lokunkundun.
“Mo ti kowe bii
marun nipa esin Yoruba. Mo ti kowe nipa esu. Esin igbagbo lo yi esu pada. Esu
to wa ninu bibeli yato esu ti a n sin. Olaju awon onigbagbo yato si olaju ile
Yoruba. A o si le so pe ikan naa ni esu ti Yoruba nigbagbo ninu ati esu to wa
ninu bibeli pelu kuraani. A o le fi won we ara won, ko seese. A kan n tan ara
wa je ni.
“Onikaluku lo le se
esin to ba wuu, sugbon eeyan ko gbodo gbagbe orisun. Awa Yoruba ti laju sodi.
Mo maa n rin kaakiri gbogbo agbaye ni lati maa fun won lekoo nipa asa ile
Yoruba. Beeyan baa n lo Soosi tabi Mosalasi, ko nilo lati maa wo awon elesin
min in gege bii pe won o laju. Awon ti won n bu won ni won o laju.
“Olorun to da gbogbo
wa ko da wa dogba, ika wa o dogba, a o si le so pe nitori pe ika kan ko ba eyi
to ku dogba, ka wa ge e danu. Gbogbo awa omo Yoruba la ba orisa ati esin Yoruba
nile, ajogunba ni.
“Awa Yoruba, a ni
ogbon, sugbon a o lo ogbon wa mo. Opo awon to mo Pataki isese ni won wa nibi
lati sagbelaruge e, nitori e lawon Oyinbo mejidinlaadota tun se wa lati
orileede Spain. Nigba tawon eeyan n so orisirisi, mo je ko ye won pe se oogun
tabi ofo mi lo le lagbara to ki n ko awon oyinbo to po bayii wa si Naijiria.
“Asa Yoruba, ti won
fi ko wa pe ka maa se otito lo je ki won nigbagbo ninu mi, ti won si tele mi wa
si Naijiria. Ooto ti mo fi ko won sona isedale ati isese ile Yoruba, bi a se n
se, lo wu won lori lati wa ba was ii.”
Ojogbon Salami ni ki
asa ati isedale Yoruba ma baa parun lo je koun maa tan an kaakiri agbaye, lati
mo pee sin kan wa, tawon eeyan tun gbodo maa se agbelaruge e, esin Yoruba ni,
tawon eeyan n gba a ni towo tese.
“Mo ti ba Asa yi
debi pe ijoba orileede Slovenia fi sinu iwe ofin won gege bi okan lara awon
esin ti won n sin. Won ni ninu awon esin tawon fowo sii, orisa wa nibe. Ministry of Internal Affairs so pe awon
fowo si esin orisa. O wu mi pe kawon omo Yoruba min in naa le se iru eleyi ti
mo n se yi. Yoruba laju, sugbon o seni laanu pe bi a se laju sii, a o tele ona,
nitori pe won ro pe nipa esin nikan ni asa Yoruba.”
Ni ti ile asa ile
Yoruba ti won si naa, o so pe “Eyi ti a n se lonii ni a n pe ni sisi ile Asa
Ile Yoruba, ti a se akosile ninu iwe, ti a n pe ni Centre for Yoruba
Traditional Culture, nibi ti a ti ma maa se orisirisi nkan ti awon eeyan maa fi
mo pe asa Yoruba si wa laye, ko kuu.
“Awon eeyan maa ri
orisiri nkan bi eyi tawon onifa n lo, tawon oni gelede n lo, tawon eleegun n lo,
atawon nnkan to ba je mo asa ibile Yoruba ni won maa ba nibi. Ti awon olorisa
ba ni ipade lati se, won le se e nibi. A tun lo anfaani gege bi ajo
(foundation) to je pe awon to ba nisoro to je mo ti ibile, nkan to ba ye ka se
fun won la maa se e."
Nigba to n soro nipa
onigbowo, Ojogbon King so pe “Ijoba ko se onigbowo e, emi funra ni mo se
onigbowo e, nitori pe nnkan ti mo nigbagbo ninu e ni, ijoba ko si da sii. Eyi
to wa nibi kere si eyi ti mo ko si Oke Ata. Eyi to wa niluu Oyinbo naa tun ju
gbogbo eyi to wa nibi lo.
Okunrin naa loun ko
le gba ijoba nimoran nitori pe won ni asoju, iyen minisita ati komisana nipa
asa ati ise, ise won si ni lati rii daju pe asa ati ise wa ko pare, ti ko si
seni to le ko won bi won se maa sise won, nitori pe won kaju e ni won se fi won
se asoju naa.
O ni boun se mo toun
n se loun se n se e, toun ko se le fun won lamoran nigba toun ko si ninu
isejoba, tabi alaforolo won. O so pe kawon omo Yoruba ma gbagbe pe asa ibile
Yoruba, adayeba ni, nnkan ti won fi bi won ni, won o si gbodo gbagbe e.
Nipari, o ni gege bi
nnkan ti Yoruba fi n ko awon omo won, “Omo Yoruba kii jale, kii puro, kii se
sogun-dogoji. Nitori e lo se je pe ti awon Oyinbo ba ti ri eni to n se otito
peluu won, ko sibi ti won o le baa de. Ooto ti mo ni lo je kawon oyinbo to po
to yi tele mi wale, ko seni to seru e ri, e loo wadi e. Ko si esin teeyan n se
laye yi ti Olorun ko gbo adura e. Ki elesin kan ma bu elesin keji, Olorun ko fe
iru e. Ki orisa atawon emi ti a n sin le gbo adura la se n sin won, kii se lati
fi figagbaga.”
No comments:
Post a Comment