E ma ba wa loruko je o – Funaab - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 15, 2017

E ma ba wa loruko je o – Funaab

Igbimo isakoso ati idagbasoke fasiti ogbin, Federal University of Agriculture Abeokuta, FUNAAB ti ke gbajare sita pe ileewe naa ko lowo si iwa abuku ti won ki kan an lojo Abameta Satide to koja yii.
 
Gege bi atejade ti alukoro ileewe naa, Arabinrin Emi’ Alawode fi sowo s’AWIKONKO lojo Isegun Tusde onii, o so pe lopin ose to koja ni won lawon kan fesun kan okan lara awon awako won pe o fi moto ileewe naa ko awon eru to lodii sofin, to si je pe se ni won se fayawo e wole.

Ninu leta naa, o so pe, “Won ti pe akiyesi igbimo isakoso ileeko wa si nnkan ti won loo sele lojo Abameta Satide, iyen ojo kejila osu yii si bi won se so pe okan lara awon awako wa n lo moto ileewe lati fi ko eru ti ko bofin mu.

“Agbegbe Olorunda nipinle Ogun ni won so pe awon osise ajo to n ri s’ofin, iyen law enforcement agents ti mu awako yii pe awon eru to ko sinu moto to je tileewe wa lodin sofin, to si tun je se loo se fayawo e wole sipinle naa.”

O tesiwaju pe igbese ti n lo lowo lori e, nitori tawon ti yan awon ti yoo topinpin lati mo boya looto ni nnkan tawon gbo naa, bo tile je pe awon ko tii le fidi e mule, bee lawon yoo gbawon ajo naa laaye lati sise iwadii won bo ti to, ati bo ti ye.

O wa fi kun oro e pe iwa omoluabi tawon fi n sakoso ileewe naa lo han lara awon akekoo won jake-jado orileede yi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI