Kasnaty ra moto nla meji laarin osu, won ni kii soju lasan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, August 15, 2017

Kasnaty ra moto nla meji laarin osu, won ni kii soju lasan

Iroyin kan to n lo kaakiri igboro Abeokuta nipinle Ogun bayii ni ti gbajumo sorosoro kan, Kolawole Atanda adejojo tawon eeyan tun mon on si Kasnaty ti won loo ra moto olowo nla meji laarin ose meta sira won.
 
Kii se bo se ra moto naa lo n ya awon eeyan lenu, bi ko se ona to fi ri owo ra awon moto naa ti won ni Lexus loruko awon moto mejeeji naa, eyi ti won ni ayokele e lo koko ra, ko to di pe o ra jiipu e, lai kii se pe o takan fi ra min in.

Bawon kan se n so pe oro okunrin naa kii soju lasan, nitori ti won so pe ko sona min in to fi n ri owo ju idi ise sorosoro to yan laayo lo, bee lawon kan n so pe o see se k’okunrin naa dogbon soro ara e labele ni.

Gege bi awuyewuye to ta si AWIKONKO leti lose to koja, ohun ti a gbo ni pe nigba to maa koko ra Lexus ayokele ti won ni alawo dudu ni yii, Honda Accord alawo eeru kan lo n lo tele, kii se pe o ta moto naa ko too di pe o ra a tuntun yi.

Bo tile je pe won ni Kasnaty ko fee se e ni alariwo pe kawon eeyan le mo nnkan to n lo, sugbon tawon to sunmo okunrin naa so pe se lo paaki moto Honda EOD naa sile, to si dogbon bi e ni pe se loun ta a fi ra tuntun.

Ohun tawon eeyan n so nigba naa ni pe o ta moto funfun fi ra dudu, eyi to je kawon eeyan maa fuura pe bi ko ba nidi, eeyan ko le wo sunsun lati so pe nnkan dudu lo ku toun fe maa lo, to si keyin si funfun.

Ko pe sigba naa ni Kasnaty tun ra jiipu Lexus, ti won so pe owo moto naa le ni milonu meta naira, to tun je alawo pupa lai kii se oni sango. Ohun tawon araalu n so ni pe adiitu kan wa lori bo se je pe moto lokunrin naa kowo ra bayii.

Awon kan tun so pe o ti le lodun meta ti Kasnaty ti pa ile e to n ko lowo ti, ti ko si ya sidi e. won ni kaka ko ronu lati pari ile e yi, moto lo n kowo ra kiri, to si n ko kaakiri bi eye.

Ibeere tawon eeyan n beere ni pe nibo lokunrin tawon eeyan n gba tie lowo lori redio ati telifisan kaakiri bayii ni pe, nibo lo ti ri owo to fi n ra awon moto yi le ara won?

Bo tile je pe ohun t’AWIKONKO n gbo ni pe bokunrin naa se n wole awon wooli kaakiri, bee lo tun n wole awon alaafa lati loo se awon ise akanse. Lara awon wolii ti won lo n sise fun un ni Wolii kan ti won pe ni Abiodun Akanni, bee ni Alaaji kan ti won n pe ni Olororo naa ko gbeyin ninu awon to wa nidi boju okunrin naa se n dan an.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI