Iya atomo to n ta igbo wo gau ni Awa Ijebu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, August 14, 2017

Iya atomo to n ta igbo wo gau ni Awa Ijebu

Se lenu ya awon eeyan ti won wa ni ogba awon olopaa to wa ni Eleweran niluu Abeokuta nigba ti won safihan arara meji,ti won je Iya atomo,esun ti won fi kan won ni pe won ko nise min in ti won se ju igbo ti ta loo.
 
Mulika Alaba ni Iya n je nigba tomo e n je Olamide Saliu,niluu Awa Ijebu la gbo pe awon olopaa ti rowo to awon eeyan naa,won ni won si ti nidi e, ojo tipe, ti won ko si nise min in ti won n se.

Gege bi a se gbo, won ni Oba ilu Awa Ijebu lo ta awon olopaa lolobo pe ki won wa mu obinrin naa, nitori igbo to n ta, o fi n se agbodegba fawon adigunjale ni.

Won lopo awon to maa n wa si aburi ti Obinrin naa ti n ta igbo yii nise won ko mo, ti won si n je kawon adigunjale wole siluu naa.Loju ese si lawon olopaa ti gbe igbese ti won si wa ibi ti obinrin naa ti n ta igbo kan, ti won si muu peluu omo e.

Nigba to n ba AWIKONKO soro, obinrin naa so pe o ti le ni odun meji seyin toun ti ta igbo naa ati pe oun nikan loun da ta sugbon omo naa rin arifesesi lo se je ki won mu oun lojo ti won moun naa.

Bakan naa lo tun salaye pe oun ni onibara to maa n gbe igbo naa wa foun lati Ondo, kii se pe oun fi daluru, ise toun mo nipa e ni. O wa ro awon olopaa pe ki won dariji oun, bi won ba foun sile, oun ko ni pada senu e mo.

Nigba to n soro, Komisanna awon olopaa nipinle Ogun so pe obinrin yii atomo e yoo foju bale ejo laipe nitori awon mejeeji jo n ta ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI