Abibat to bimo nibi ayeye Ojude Oba, Orisa agemo lo wa nidi e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 11, 2017

Abibat to bimo nibi ayeye Ojude Oba, Orisa agemo lo wa nidi e

Bee ni Gomina Amosun tun fi egberun lona ogorun (N100,000) naira taa lore

Idunnu subu lu ayo awon omo bibi ilu Ijebu Ode lojo Aiku Sande to koja lo nigba ti iroyin Arabinrin kan, Abibat Ayanlola to bimo obinrin lanti-lanti lakoko ti ayeye Ojude Oba n lo lowo kan sawon eeyan. 

Bawon eeyan se n dupe lowo Olorun, bee lawon kan n so pe awon orisa alagemo merindinlogun atawon orisa ile Yoruba ko pada leyin ayeye isembaye ajogunba naa nitori apeere rere ni omo tuntun naa je fawon. 

Gege b'AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago kan ku iseju metala osan ojo naa, lakoko ti ayeye naa ti wo opo awon eeyan to fi mo awon alejo lara nisele kayeefi naa sele. 

Ohun taa gbo ni pe, Abibat to je okan lara awon omo egbe regberegbe to farahan niwaju Kabiyesi Awujale, Gomina ipinle Ogun atawon alejo lojo naa lo dide lati loo to, nitori ti ko mo bi ara e se ri. 

Won ni ko too di pe omo bere sii mu Abibat to wa lati eya Awori, Iyen ni Yewa, eni ti won ni ko le se ko ma yoju sibi ayeye olodoodun naa, lo ti n fese rajo kaakiri, nitori ti inu e dun.

Kani Abibat mo pe ojo naa loun maa bimo ni, o seese ko je pe osibitu lo maa wa, ko ma si lanfaani lati yoju sibi ayeye todun yi, nitori taa gbo pe ojo kejila, iyen ojo Isegun ola yi ni dokita ti so pe o maa bimo. Eyi ni ko je ko ronu pe o seese koun bimo lojo naa. 

A gbo pe asiko ti Abibat n pada bo lati ibi to ti loo to, to n gun oke loo jokoo pada saaye e ni omo bere sii mu, to si n lo inu mole, sugbon tawon eeyan ko tete fura. 

Ijo ati gbogbo bi won se so pe Abibat n se lojo naa ni won loo fa tawon eeyan toro naa soju e ko fi kobi ara sii pe omo lo n mu, afigba to yo iro ara e sonu, to si pariwo pe "E saanu mi, e ran mi lowo."

Eyi lo faa tawon eeyan fi sare dide mon on paapaa bi won tun se ri ori omo tuntun to yo labe e. Bee ni won sare gbe e lo seyin gbagede legbe ibi to ti loo to, ti won si gbebi fun. 

Se nisele naa dabi ere ori itage, tabi ka so pe fiimu agbelewo loju opo awon eeyan nigba tawon kan to mo nipa isese tun se n pogede, ti won pofo pe ko le bi omo naa. 

Nigba ti akoroyin wa maa fi debe, obinrin kan lara awon regberegbe Bobagbimo Obinrin Akile so pe kii se ibi tawon eeyan le de lati loo woran. Ko si pe ti moto osibitu jenera to n ri sisele pajawiri fi waa gbe e lo pelu omo tuntun maa lati loo toju won. 

Abibat, eni odun mejilelogbon to nise olopo loun n se nigba to n boniroyin soro lojo Monde to tele, o ni oun ko nii lokan pe ojo naa loun le bimo nitori ti dokita ti so pe ojo kejila osu yi loun yoo bimo. 

O lara oun bale nigba toun n pada bo lati ibi toun ti loo to, Lo fi jokoo lati sinmi, sugbon lesekese loro naa yiwo moun lowo, to si di pe omo jade lebe oun, ki won too sare gbe oun kuro lo segbe gbagede. 

Bo tile je pe gbogbo akitiyan awon eeyan lati je kiroyin Abibat Ayanlola to bimo lakoko ti ayeye Ojude Oba olodoodun nni maa n waye n lo lowo kan si Oba Sikirulai Adetona, Awujale tile Ijebu ati Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun lo ja si pabo nigba tawon to tuko eto naa ko jale lati fi to won leti. 

Ojo keji ni Gomina Ibikunle Amosun ti ran komisana foro ilera, Babatunde Ipaye lati loo sabewo si Abibat, ko si fun un ni owo egberun lona ogorun (100,000) naira lati fi toju ara e. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI