Gbogbo aye n sedaro Jenera Adekunle, agba olorin juju to ku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, September 11, 2017

Gbogbo aye n sedaro Jenera Adekunle, agba olorin juju to ku

Opo awon to mo gbajumo olorin Juju nni, Oloogbe Omoba Adeyinka Adekunle topo mon on si Jenera Adekunle, eni to so orin Juju kiko dirorun nigba aye e ni ko le gbagbe awon ipa to ko lodun 60s si 70s, eyi to je ki won si maa sedaro e titi di asiko yi. 

Ojo Abameta Satide to koja lo lohun ni baba agba eni odun merinlelaadorin, 74 naa dagbere faye nileewosan ijoba apapo FMC to wa niluu Abeokuta leyin ose meta ti won ti daa duro. 

Gege b'AWIKONKO se gbo, aisan ojo ogbo ni won loo se omo bibi ilu Abeokuta naa, ko too di pe won gbe e mo sileewosan lati gba itoju. 

Ohun taa gbo ni pe, ara Jenera Adekunle ti n ya, to si ti n rin, to tun n dide yagbe, iyen awon nkan to ko lee se tele, nitori ti won so pe se ni aisan naa fee yi si ropa rose. 

AWIKONKO gbo pe baba yi ko fu awon ebi atawon omo lara pe asiko ti to lati ki aye pe o digbose lo je ko maa fi gbogbo agbara se awon nkan to n se.

 A gbo pe ipalemo bi won yoo se se ayeye ojo ibi odun marundilogorin, 75 ni won si n ronu e pe awon yoo se ninu osu to m bo nitori ti won so pe ojo kejilelogun osu kewaa gangan lo maa pe odun marundilogorin.

Lesekese ti Jenera Adekunle ti ku la gbo pe won ti gboku e lo si mosuari lati se ipalemo bi won yoo se sinku e. Okan lara awon aburo e, Ogbeni Femi Adekunle nigba to n soro so pe oun yoo je ka mo bi eto isinku yoo se lo leyin tawon ebi ba ti fenukoo. 

Ko seni to gbo orin Jenera Adekunle nigba naa ti ko nii kan saara sii nitori ona to gbe orin ti e gba, pelu awon ilu agbosogbanu to fi kun un. 

Lara awon ti oloogbe naa n ba figagbaga lakoko naa ni Sunny Ade,  Ebenezer Obey,  Wale Glorious, Idowu Animashaun, Toye Ajagun, Dele Abiodun, Popular Jingo, Femi Ajasa atawon min in. 

Awon bii Segun Adewale, Shina Peters atawon min in la gbo pe oloogbe naa so di olokiki nidi ise orin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI