Emi o darapo mo egbe oselu Accord o - Paseda pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 8, 2017

Emi o darapo mo egbe oselu Accord o - Paseda pariwo sita

Oludije fun ipo gomina ipinle Ogun lodun 2015 ati oludasile ajo alaanu Paseda Legacy Foundation, Omoba Olarotimi Olatunde Paseda ti pariwo sita pe oun ko darapo mo egbe oselu Accord tawon eeyan n gbe kiri. 

Paseda soro yi ninu atejade ti akowe iroyin e, Ogbeni Michael Ogunsiji fi sowo s'AWIKONKO lai pe yi, o ni iro ati aheso to jinna si ooto niroyin ayederu naa. 

AWIKONKO gbo pe pelu bi egbe oselu Accord se n gbile si kaakiri ipinle Ogun, paapaa lorileede Naijiria, tawon oloselu si n sare loo foruko sile lati rowo mu ninu idibo odun 2019, lo fa a tawon eeyan fi ro pe gbajumo oloselu naa ti n gbero lati loo darapo egbe oselu Accord.

Ninu atejade naa lo ti so pe aheso naa kii se ooto rara nitori pe Omoba Rotimi Paseda gan an ni eni igi leyin ogba to n sagbateru egbe oselu Unity, UPN kaakiri orileede Naijiria. 

O ni bi eyikeyi ayipada ba fee waye ninu egbe oselu UPN, tabi to jo mo oro oselu nipa oun, oun yoo je kawon araalu mo nipa e. 

Bee lo gbawon araalu lamoran pe ki won ma se ni iporuru okan, tabi se iyemeji latari awon ayederu iroyin to n lo kaakiri ori ero ayelujara, intaneeti. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI