Eyi ni bowo olopaa se te Ajoke gbomogbomo l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, September 11, 2017

Eyi ni bowo olopaa se te Ajoke gbomogbomo l'Abeokuta

Bawon Yoruba se n so pe asegbe kan o si, ase pamo lo wa, bee naa ni won maa n so pe bi iro ba lo logun odun, ojo kan soso looto yoo de ba, oro yi gan an lo lo nibamu pelu bowo olopaa ipinle Ogun se te odomobinrin eni odun mejidinlogbon, Ajoke Owolabi, ati pe ka ni oun gan an mo pe ojo naa lasiri oun maa tu ni, o see se ko ma gba adugbo naa koja.

Ni nnkan bi aago mesan aabo aaro ojo Isegun Tusde ojo kokandinlogbon osu to koja lowo te Ajoke ladugbo Oke-Ibode, Abeokuta nigba tasiri e tu sawon araadugbo naa lowo.

Ohun taa gbo ni pe, omodebinrin omodun meje, Rachael Olorunsola ti Ajoke ji gbe lodun 2015, sugbon ti ori koo yo ninu osu keje  odun yi lo ti asiri e lakoko to koja niwaju ita ile won laaro ojo naa.

AWIKONKO gbo pe, Rachael lo n sere pelu awon ore e niwaju ita lojo naa ti Ajoke fi koja, lesekese lomo naa ti da a mo, to si so fun obinrin kan ti won jo n gbe ile ti won n pe ni iya Rafiat pe eni to ji oun gbe lo n lo yen, Anti Ajoke loruko e. 

Iya Rafiat tawon eeyan tun mo si Iya elewa nitori ounje ewa alagbado to n ra lo so pe ko gbe enu e dake, sugbon tomo naa so pe oun mo nnkan toun n so, eyi lo mu ki iya eleso pe Ajoke, toun naa si boju weyin, boro naa se jo gate re e. 

Iya eleso la gbo pe o ranse pe iya Rachael ninu yara to wa, to won si sare too Ajoke lo, sugbon nnkan to so fun won ni pe oun ko ni Anti Ajoke, Ki won wa eni to n je oruko naa siwaju. 

Rachael lo je ko ye won pe ti won ba wo owo osi e, won a ri oruko e, Ajoke to ko sowo e pe oun ko lee paro mo, looto nigba ti won yee wo, Ajoke Oshodi lo ko sowo e. 

Boro naa se di ariwo re e, tawon araadugbo si pe le e lori, ti won bere sii lu, ko pe ni won lawon omo ibeji tojo ori won ko ju odun marun un lo de pe Anti Ajoke si ra daya (Sweet) fawon pe oun bo wa a mu won lo sibi kan.

A gbo pe pati kan ni Ajoke wa a se ninu osu keje odun yi, to si mu Rachael dani, nigba ti Rachael rii pe anfaani re e lati pada sodo obi oun leyin odun meji lo ba fogbon sa lo mon on lowo. 

Oju ona la gbo pe Rachael ti so fun Ajoke pe bata oun ti jabo, ni won so pe Ajoke ti jagbe mon on pe ko loo mu bata e, bo se di pe Rachael sare wo ahoro kan re e, to won si wa a ti. 

Iya Rafiat nigba to n b'AWIKONKO soro so pe "Ibi ni mo jokoo si ti mo n sa ewa, nitori ewa oloka ni mo n ta, sadede ni Rachael ni ki n wo Anti Ajoke to ji oun gbe loo s'Ekoo. Mo ni ko gbe enu e dake, sugbon o ni ti m ba ye owo e wo, oruko e wa lowo e. Mo pe e lakoko, o boju weyin, mo pe e leekeeji, o boju weyin, bo ba sare dide lati loo ba.

"Igba ti mo sunmo ni mo beere lowo e pe soun lo n je Ajoke, ati pe se o mo Rachael ri, sugbon o loun ko ni Ajoke, bee loun ko mo Rachael ri. Nigba taa wo owo e, la ri Ajoke Oshodi lowo, Ki n to pariwo sita. Lesekese lo so pe ka se oun jeje, to si jewoo fun wa."

Iya Rachael to tun n tomo kekere kan lowo nigba to n b'AWIKONKO soro so pe nigba tawon ko ri Rachael lodun 2015 tawon n wa a kaakiri, lawon loo foro naa to awon olopaa Ibara leti. 

Ninu oro e, o so pe "Ko sibi ta a wa omo yi de nigba yen, nigba taa de tesan olopaa Ibara, se lawon olopaa tun ti baba e mole fojo meji pe o seese ko mo nipa e, ko je pe se lo fomo soogun owo, to fe maa dawon olopaa laamu. Ojo keji ni won fi sile. 

"Oke Igbore la n gbe nigba to ji omo mi gbe, ko too di pe a ko kuro nibe wa si Oke-Ibode. Eni kan to rii nibi to ti n rin kaakiri lo satona e de odo wa ninu osu keje. 

"Nigba tawon araadugbo bere sii lu Ajoke lawon kan so pe kawon loo fa le awon olopaa lowo. Ojo keji ni won pe wa si Eleweran lati beere oro lowo wa. O jewo pe looto loun ji Rachael gbe, ati pe oun kan fe maa toju e bi omo ni. 

Gbogbo akitiyan lati ba Baba Rachael tawon eeyan tun mo si Ariya, eni ti won nise Radioniiki lo n se ladugbo Oke Igbore soro lo ja si pabo, nigba taa pe lori aago e, 09095432413 to ni ka wa ba oun nile laaro ojo Tosde to koja yi, nigba ta a de be, won loo ti jade, sugbon titi di asiko ta a sakojopo iroyin yi lokunrin naa ko tii gbe aago wa. 

Awon araadugbo naa lo je ko ye wa pe aya okunrin naa lo n ja lati ba oniroyin soro. 

Ni bayii, Komisana olopaa ipinle Ogun, Ahmed Iliyasu so pe Ajoke ti wa lodo eka olopaa to n ri soro ajinigbe ategbe okunkun, lai pe ni won yoo si foju e bale ejo. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI