FUNAAB ti bere iforukosile fawon akekoo tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 8, 2017

FUNAAB ti bere iforukosile fawon akekoo tuntun

Ileewe giga fasiti to n kekoo nipa ogbin, Federal University of Agriculture, Abeokuta, FUNAAB ti bere iforukosile igbaniwole fawon akekoo tuntun fun saa ikekoo odun 2017/2018.

Gege bi atejade ti olugbaniwole agba, Dokita Arabinrin L.O. Onwuka fi sowo s'AWIKONKO lojo Tosde to koja yi, o ni awon nipele 100level, 200level ati 300level laaye si sile fun lati foruko sile lori ero ayelujara won http://admission.unaab.edu.ng.

Dokita Onwuka lawon to kopa ninu idanwo UTME to koja yi, ti won si ni ogosan (180) maaki, o kere ju,  iyen fawon to ba fee kekoo nipa ogbin ati igba maaki fawon to ba fee kekoo nipa imo ero (Engineering, Sciences and Veterinary programmes) nikan lo lanfaani lati fi gbogbo oro nipa won (Bio Data) sile ki asiko too lo.

Ojoru Wesde, ojo kefa osu yi ni eto naa bere, ti yoo si pari lojo kokanlelogun osu yi, sugbon aaye si si sile fawon to ba fee wole si ipele 200level ati 300level titi di ogbon ojo osu to m bo. 

Be o ba gbagbe, ose to koja ni won fi igbelewon igbaniwole fun saa ikekoo odun yi, 2017/2018 sita fawon akekoo tuntun to ba fee wole sileeko naa.

Gege bi atejade ti igbimo idagbasoke ileeko naa fi sita laaro oni, eyi ti eda e te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe ki igbaniwole saa ikekoo tuntun yi le lo bo se ye, awon ni lati tete fi sita fawon eeyan lati tete mo ipinu won paapaa awon to mu FUNAAB gege bi akoko ninu idanwo Jamb to waye laipe yi.

Ipinu yi la gbo pe o waye leyin abajade ipade to waye laarin awon alase ileewe naa ati Minisita foro ekoo lorileede Naijiria.

Ohun taa gbo ni pe ipele meji ni eto igbelewon igbaniwole naa wa, eyi to je pe maaki ogun din ni igba (180) ni ipele akoko, nigba ti igba maaki (200) je ipele keji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI