Eyi ni bi tirela se te Seyi omo egbe awako pa niluu Ijebu Igbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 6, 2017

Eyi ni bi tirela se te Seyi omo egbe awako pa niluu Ijebu Igbo

Tolu Ogunlana, Ijebu Igbo

Nise ni gbogbo agbegbe Station niluu Ijebu Igbo daru lojo Isegun Tusde to koja latari bi won se so pe awako tirela kan te okan lara awon omo egbe onimoto ti Road, iyen NURTW pa.

Okunrin naa ti won poruko e ni Seyi la gbo asiko to n palemo awon eru kan to fe e ko lo silu Eko la gbo pe awako tirela naa te nitekute ni nnkan bi aago merin aaro ojo naa, to si gbabe dagbere faye.

Ohun ta a gbo pe o fa a tisele naa tun fi da wahala sile ni bi won se so pe opo awon moto to koja nibi ti tirela naa gba Seyi si ni won tun te e koja, ti gbogbo eya ara e si jera mole.

AWIKONKO gbo pe bi kii ba se pe nitosi moto ti Seyi fi n sise nisele naa ti waye, o seese ki won ma mo pe oun ni, ati pe ni nnkan bi aago mefa aabo aaro ojo naa lawon eeyan to sese mo, ti won lawon onimoto bere sii pe ara won lori aago.


Pelu ibinu la gbo pe awon omo oni moto yi fi da wahala sile lojo naa, to si gba awon olopaa ni opolopo wakati ki won to o dawon lowo ko nitori ta a gbo pe opo awon to n koja lasiko naa ni won fara kaasa egba lati owo awon eeyan naa.

A gbo pe o ti n lo bii owo irole kawon to ni soobu ati ileese ladugbo naa to o ri aaye lati silekun lojo naa, nitori ta a gbo pe onikaluku won lo sa asala fun emi ara won.


Agbenuso fun ileese olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n fidi isele naa mule fawon oniroyin, o so pe looto nisele naa waye, ati pe titi di asiko yi lawon ko tii le so pato nipa eni to wa tirela naa ati tirela to je.

O lawon olopaa lo gbe oku naa kuro loju titi to wa lo si mosuari nitori se lawon eeyan faso bo o mole ti ko si boju mu to. Bee lo so pe iwadii si n lo lowo lati mo eni to sise buruku naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI