Olowolabi ji omo oga e gbe nitori owo to fee fi se oku iya e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 6, 2017

Olowolabi ji omo oga e gbe nitori owo to fee fi se oku iya e

Sunday Agbaje, Eko

Iyalenu loro odomokunrin eni ogbon odun kan to won poruko e ni Olowolabi Williams si n je fawon eeyan to gbo nipa bo se ji awon aburo oga e meji gbe lojo Satide to koja lo lohun, lati fi gba owo lowo awon ebi won nitori ayeye oku mama e to fe e se.

Ohun ta a gbo ni pe agbegbe agbegbe Oniru ni Victoria Island nipinle Eko ni Olowolabi, eni odun mejidinlogoji (38) atawon ore e ti ji awon aburo oga e meji ti won poruko won ni Hillary Chukwudumebi ati Rebecca Omokaro, sugbon tasiri won pada tu sawon olopaa lowo lojo Sande ose to koja, leyin ti won ri won ko lagbegbe Agodo, Alara-Ogijo nipinle Ogun.

AWIKONKO gbo pe Olowolabi ti won nise alagbawa (driver) lo n se, lo so fun oga to n ba sise wi pe ko ya oun lowo egberun lona ogorun naira (100,000), nitori toun fee fi kun owo to wa lowo oun lati fi se oku mama oun to n bo lona, sugbon ti oga e naa so pe ko si owo nile.


Oga e la gbo pe o so fun Olowolabi wi pe oun sese fowo sowo ni, nitori naa ko si ni suuru foun digba ti owo yii fi wole foun, sugbon ti won ni Olowolabi gba oro naa sodi.

Eyi lo fa a ti won ni Olowolabi se loo fi oro e lo awon eeyan, ti won ni lara awon to foro naa lo, iyen Akintunde Amala gba a lamoran wi pe ko ji aburo oga e gbe, ko si fi beere owo, loun naa ba gba sii lenu.

AWIKONKO gbo pe Akintunde lo ba Olowolabi wa awon eeyan ti won tun le ran an lowo, iyen Segun Teluwo ati Ayo Akinola, ti won si loo ji Rebecca ati Hillary gbe nile won to wa ni Oniru lakoko ti won lawon yen n jaye ori won lo pelu moto jiipu Ford, ti nomba idanimo e je LND995ES.


Ibon la gbo pe won fi pada won, ti won si dari won lo si agbegbe Alara-Ogijo nipinle Ogun nibi ti won ti lero wi pe asiri won ko nii tu, sugbon tawon olopaa se ofin toto, ti won si ri won, ko too di pe  adele Komisana olopaa ipinle Eko foju won han fawon oniroyin.

A gbo pe ogun milionu naira lawon eeyan naa lawon fe e gba kawon to le fi won sile, ti won si n dunkoko mo won pe bi won ko ba tete san owo naa, pipa lawon yoo pa Dumebi ati Hillary.

Idi ni yii ti won fi loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si bere ise lesekese. Foonu ni won lawon olopaa fi se atona won debi ti won wa lojo naa.

Nibi ti won lowo awon olopaa ti te won ni won ti ri ibon ilewo kan, obe nla kan, kaadi ti won fi n gbowo (ATM) atawon nkan min in gba lowo won, bee ni won tun gba moto naa pada.

Ohun ta a gbo ni pe ojo Monde to tele lawon olopaa fi Akintunde sile wi pe ko maa lo sile, nitori ti ko mo nkankan nipa esun ti won fi kan an, tawon olopaa ko si so idi ti won se fi sile, nitori ti won loun nigi leyin ogba lori bi won se ji awon eeyan naa gbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI