Nitori foonu; Odunlade sa Kaka pa l’Atan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 6, 2017

Nitori foonu; Odunlade sa Kaka pa l’Atan

Sunday Agbaje; Eko

Kayeefi loro okunrin kan ti won poruko e ni Odunlade Adewale ti won lo n sise kafinta si n je fawon olugbe ipinle Ogun atawon to gbo nipa iroyin naa si n je fun won lori bi okunrin naa se sa ore e, Moruf Lawal ti won tun n pe ni Kaka pa, to si tun kun ori e si wewe nitori foonu ti won so pe won n wa.

Oku Kaka
Gege b’AWIKONKO se gbo, adugbo kan ti won n pe ni Lemomu Kajola, Ile-Ise Bus Stop ni Atan-Ota ni won nisele naa ti waye lojo Aje Monde ose to koja ni nnkan bi aago kan si aago meta oru tawon araadugbo ti sun.

Ohun ta a gbo ni pe foonu ore won kan ti won pe ni Femi ni won n wa loru ojo naa, ti won si so pe o seese ko je pe Odunlade lo muu, sugbon to gba oro naa sodi wi pe won fi ole kan oun.

Nibi ti won ti n fa oro naa la gbo pe Kaka, eni odun mejidinlogoji (38) ti fa ada yo, sugbon ti Odunlade gba a lowo e, to si ge owo e mejeeji, to tun sa a lada na lori welewele bi eran odun Ileya. Lesekese ni won so pe Femi ti na papa bora nigba to rii pe oro naa ti koja oju lasan.

Iyalenu lo je pe bi Odunlade se pa Kaka tan, lo ba tun bere sii pariwo sawon araadugbo wi pe ki won tete jade, nitori toun ti pa ore e oun, toun si tun fe e pa eeyan repete sii ki ara oun to o bale.

Were ni won koko pe e, sugbon tawon to mon on daadaa ladugbo rii, ni won too mo pe oun ni, ko too di pe awon eso ojulalakanfinsori fijilante ipinle Ogun, iyen awon VSO to wa nitosi rii, ti won si rowo to lateyin.

Lara awon agbaagba ladugbo ti won soro lori isele naa je ko ye wa pe ore timotimo ni Odunlade, Lawal ati Femi, ti won nise awon to n tun jenereto se lo n se, ati pe won jo maa n muti ati igbo po ni.

Okunrin naa so pe ibi ti won ti loo muti ni won ti n bo, ki won to o da oni keke maruwa kan duro lati gba owo lowo e, sugbon to je pe Imaamu kan lo da si oro naa, to si bawon pari ija, toni kaluku si ba ti won lo.

Nibe ni lo so pe Femi bere sii wa foonu e, to si loo sile Kaka lati loo bere foonu, sugbon to so pe oun ko loun muu, ko too di pe won lo sabe ihere kan ti won ni Odunlade maa n sun si nitori ko nile to n gbe lati lo beere lowo e.

Se loro naa doju ru nigba ti won de odo Odunlade, ti won si bere sii fa a mora won lowo, ko too di pe Odunlade gba ada ti Kaka mu dani, to si fi ge apa e mejeeji bo sile, to tun sa a lori titi do fi ta teru nipa, ti Femi naa si fese fe e.

Asiko naa ni won so pe awon fijilante VSO sise won koja, ti won si muu nibi to ti n pariwo soke, bo tile je pe ada ba okan ninu won lowo, sugbon oju e da nigba to mo nkan to se tan.

Agbenuso fawon fijilante Kolawole Yusuf nigba to n jeri soro naa so pe kani awon osise awon ko rin sasiko nigba naa, o seese ko tun ti gbemi elomin, ati pe awon osise awon lo gbe e lo sodo awon olopaa to wa ni Onipanu lati fi to won leti, ti won si gboku naa lo si motuari.

Bakan naa ni Abimbola Oyeyemi to je Komisana olopaa ipinle Ogun so pe looto ni ati pe awon meteeta ma n dawon eeyan lona lati gba owo lowo won, o ni ile oti ni won ti n bo lojo naa ko too di pe won koju ija sira won.

O so pe alaganna ati oni warapa ni won pe Odunlade, sugbon tawon kan je ko ye AWIKONKO pe aisan warapa nikan lo n yo lenu, ati pe nitori aisan naa lawon ebi e fi le e kuro nilu won nipinle Ondo, ko to o sa kuro nibe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI