Tirela te eeyan merin pa n'Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 6, 2017

Tirela te eeyan merin pa n'Ibadan

Tayo Adio, Ibadan

Ojo ibanuje lojo Abameta Satide to koja yi je l'oja Moniya niluu Ibadan nigba ti tipa oniyepe kan te eeyan merin nitekute, ti won si gbabe dero orun alakeji, tawon mewaa min in tun se bee dero osibitu lesekese.

Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni bureeki (brake) tirela naa lo ja lori ere, to si se bee lo o kolu awon eeyan ni Moniya, lopopona Iseyin, ipinle Oyo.

Lesekese la gbo pe ariwo ti ta tawon toro naa soju won si sa asala fun emi ara won, nitori ki won ma baa padanu iku ojiji pelu bi odun se n sunmo etile, tawon eeyan tun ti n palemo ayeye odun lowo.

Awon to gbe iroyin naa si wa leti so pe bisele naa se sele tan, ni won so pe awako to wa tirela naa ti poora, ti ko si seni to le so pato lori bo se rin in.

AWIKONKO gbo pe moto elese meta, iyen Keke Maruwa meta ati okada marun un ti won fara kaasa ni won baje koja afenuso


Lara awon to padanu emi won ni olokada kan, omode"kunrin kan, ati okan lara awon to n taja ninu oja Moniya naa. Lesekese la gbo pe awon eeyan ti loo sibe lati loo gbe awon ti won ko tii ku lo si osibitu lati doola emi won.

Nibi isele naa
Ko pe ti won fi ranse sawon olopaa to wa lagbegbe naa lati wa a foju won to o, ti won si gboku awon to padanu emi won lo si mosuari osibitu ijoba to wa ni Ring Road, ti won si ko awon to farapa lo si woodu isele pajawiri fun itoju.

Bee la tun gbo pe awon kan to ri okunrin awako tirela naa nigba to na papa bora ni won so fawon olopaa, ti won si loo muu nibi to sapamo sii.

Agbenuso fun ileese olopaa ipinle Oyo, Ogbeni Adekunle Ajisebutu nigba to n jeri sisele naa so pe looto lawon eeyan padanu emi won, tawon si ti gboku won lo si mosuari lesekese.


Ajisebutu so pe bo tile je pe awako tirela naa koko salo, sugbon tasiri e pada tu sawon lowo nibi to sa si. O lawon ti gbe tirela naa lo sodo awon ajo eso oju popona, iyen VIO, ti iwadii si n lo lowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI