Pasito Senfuye sayeye odun keresimesi fawon alaini - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 25, 2017

Pasito Senfuye sayeye odun keresimesi fawon alaini

Ko seni to ri bi ero se po logba ati ayika ijo Treasure House of God to wa ladugbo Quarry niluu Abeokuta tii se olu ilu ipinle Ogun laaro oni ojo Monde, iyen ojo odun keresimesi ti ko ni maa gbadura fun oludasile ijo naa atawon alakoso lori bi won se fawon eeyan paapaa awon alaini lebun odun repete.

Gege b'AWIKONKO se gbo, ko din legberun merin aabo awon alaini lawon ti ijo naa labe oludasile e, Pasito Seye Senfuye, eni to ti figba kan ri je akowe owo (Accountant General) ijoba ipinle Ogun fun lebun odun naa.

Nnkan to je ko je iyalenu fawon ti nkan naa soju won ni bo se je pe won ko fi oju tabi esin tabi oro eleyameya pin ebun naa fawon eeyan, to je pe bi won se fawon arugbo, bee ni won fawon odo atawon to je pe agbalagba ni won.

Paapaa julo bo tun se je pe awon elesin musulumi ati abalaye lo po ju ninu awon to gba ebun odun naa, to si je pe gbogbo won ni won n sadura fun ijo naa.

AWIKONKO gbo pe, aago meje aaro ni won bere e pelu eto isin ranpe, ti won si tun foro Olorun bo awon eeyan.

AWIKONKO gbo pe ko din ni irinwo (400) lawon to fi aye won fun Jesu leyin iwaasu to waye nibe, tonikalu si jeri si agbara Olorun nibe, iyen bi Olorun se fowo to aye won.

Nigba to n gba enu oludasile ijo naa, Pasito Senfuye soro, Pasito Lenus Taylor so pe bo tile je pe awon ti wa lenu e ti pe, sugbon ti todun yi tun ju todun to koja lo.

Taylor to tun je igbakeji oludasile ijo naa tun so pe gege bi asiko yi se lo pelu ilana Bibeli, asiko to ye kawon to ba ni maa fun awon alaini gan an ni asiko yi, nitori ififunni dara ju keeyan maa gba lo.

O tesiwaju pe die lo fi le legberun kan (1000) lawon tawon fun lebun lodun to koja, sugbon todun yi tun le ni ilopo nitori die lo fi din legberun marun un (5000), iyen awon tawon fun lebun odun raisi (Rice) ati eran tutu (Fresh Meat).

Nigba to n gbawon eeyan lamoran pelu asiko yi, Pasito Taylor so pe kawon eeyan lo anfaani odun keresimesi ti a fi n sajoyo ojo ibi Jesu Olugbala lati fi maa mu inu awon alaini dun, nitori pe ika ko dogba.

O tun so pe Olorun lo koko bere eto ififunni, nitori pe oun lo koko fi Jesu Olugbala ta awon eeyan to da lore, nitori pe gege bi Bibeli se sapejuwo Jesu gege bi omo kan soso to ni lati fi ra iye fun gbogbo eeyan.

Lara awon to b'AWIKONKO soro lakoko eto naa so pe idunnu nla lo subu lu ayo won nitori pe awon ko lero wi pe awon yoo sayeye odun ni ile won nitori ti ko si nkan tawon le fi se e, sugbon nipa iranlowo ti ijo naa se lawon se n dupe lowo Olorun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI