Alawiye Fee Se Iranlowo Fawon Opo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 20, 2018

Alawiye Fee Se Iranlowo Fawon Opo

Gbogbo eto lo ti fe e pari bayii fun ti ayeye ojo ibi alaga ana egbe sorosoro nipinle Ogun, Ogbeni Akinyemi Olatoye tawon ololufe e mo si Alawiye Fediresan, eyi to fe e waye logbon ojo osu yi, iyen ojo Fraide ose to m bo nibi tawon agbaagba nidi ise sorosoro ati leka amuludun, to fi mo awon oloselu lorileede Naijiria yoo ti peju-pese sibe.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, gbongan ayeye ile itura CM Suites leto naa yoo ti waye nibi ti opo awon opo yoo ti gba orisirisi ebun ti won yoo maa lo, paapaa awon ebun lati fi bere okoowo.

AWIKONKO gbo pe orisirisi eto ni awon igbimo to n sakoso ayeye naa ti la kale, ninu eyi tawon eeyan yoo ti ni anfaani lati beere ibeere lowo omo olojo ibi, Alawiye ti won tun un pe ni Paito Titu.

A gbo pe won yoo yi koto lojo naa, nibi tawon to ba wa nibe yoo ti je orisirisi ebun, iyen awon to ba ra tikeeti ti won fe e fi yi koto lojo naa.

AWIKONKO tun gbo pe ayeye naa ko si fun gbogbo eeyan, bi ko se awon to ba gba iwe ipe, iyen Invitation Card nikan ni won yoo lanfaani lati wole sinu gbongan ayeye lojo naa.

Bee la tun gbo pe efe, orin ati ijo yoo po lojo naa, tawon eeyan yoo si gbadun ara won de gongo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI