Tolu Odebiyi Di Omoodo Apapandodo Nitori Ipo Gomina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 20, 2018

Tolu Odebiyi Di Omoodo Apapandodo Nitori Ipo Gomina

Beeyan ba ri bi olori awon osise gomina ipinle Ogun, Ogbeni Tolu Odebiyi se n se awon ise ti ko to sii lasiko yii, iyen awon ise to je pe awon osise abe e lo to sii, yoo mo pe ko ni ipinu meji ju bi yoo se wa oju rere gomina Ibikunle Amosun lati fa a kale gege bi oludije sipo naa lodun 2019.

Opo awon to n ri bokinrin naa se n fi taratara sise ti ko to sii la gbo pe won n fi se yeye, ti won si n so pe oju aye lasan lo n se ni gbogbo igba, paapaa to ba ti wa niwaju oga e, Amosun.

Lojo Tusde ti eto fawon olokoowo, iyen Ogun State Investors' Forum ti Gomina Ibikunle Amosun sagbekale e lawuyeye tun je jade pe ki okunrin naa lo wa ibi jokoo si, nitori pe oruko e ko si ninu iwe awon ti Amosun n pinu lati fa kale gege bi eni ti yoo gba opa ase lowo e to ba se tan lodun to m bo.

Bo tile je pe gbogbo ona ni Tolu Odebiyi to tun je omo ile Yewa n wa, pelu bi Gomina Amosun ti se se ileri pe oun yoo gbaruku ti awon Yewa lati depo naa lodun 2019, toun naa si n rin awon irin kan labele lati le je ki Amosun fa a kale, sibe, a gbo pe okan Amosun ko si lodo e.

Fawon to ba mo Gomina Amosun daadaa pelu bo se n so pe oun nikan loun mo eni ti yoo gbajoba lowo oun, yoo mo pe eni ti yoo gboro sii lenu lo n wa, ti kii se eni ti ko ni le ba soro.

Eyi lo fa a ti Amosun fi n foju sile daadaa lati mo eni ti ko nii dale e to ba fi le sagbateru iru eni be e wole, ti Tolu Odebiyi funra e si mo iru eni ti Gomina Amosun je paapaa to ba di oro oselu.

Bi Tolu Odebiyi se n lo soke, bee lo n lo sile tawon eeyan ti mo bo se n lo si n woye pe ki lo n se okunrin naa ti ara e ko bale, sugbon to je pe oun nikan loro ara e ye.

Lara awon to fisele to sele lonii to AWIKONKO leti je ko ye wa pe nigba ti Aare teleri lorileede Mexico, Ogbeni Felipe Calderon n se Idanilekoo fawon eeyan, to n wa bo se fe e mu omi, ni Tolu Odebiyi tun sare dide nibi to wa lati ba a wa omi ti yoo mu, ko too di pe awon eeyan pe e pe ko loo jokoo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI