Se loro naa da bi awada ni ile ejo
Majisireeti to fikale sagbegbe Isabo niluu Abeokuta lojo Fraide to koja nigba
ti adajo ju gendekunrin omo Ibo kan, Emmanuel Blessing sewon ojo kan gbako pelu
esun ti won fi kan an pe o yoju wo Arabinrin Dolapo Akinfenwa ti won jo n gbe
ni baluwe.
Kii se adajo naa, iyen onidajo S. A.
Soneye mon on mo ni ki Emmanuel loo sewon ojo kan, bi ko se pe ai ri owo
itanran, egberun lona ogorun (100,000) naira san lo fa a.
Gege ba a se gbo, ojo kokanlelogun
osu yo koja yi ni won ni Emmanuel to n gbe lojule kerinla, adugbo Nepa Road loo
silekun mo Dolapa lori nibi to ti n we, nitori to so pe oun loun koko gbe omi
si baluwe naa lati we, sugbon to ni Dolapo loo gbe e kuro.
Nigba ti Emmanuel n rojo niwaju
adajo, o so pe kii se pe oun mon on mo silekun baluwe naa mo Dolapo lori, o ni
oun kan ni koun gba ikekun to je paanu ni won fi se e naa, to si si leekan naa.
O loun loun koko gbe omi wonu baluwe
naa lati we, sugbon oun gbagbe nkan sinu yara, nnkan naa loun pada loo mu, to
fi je pe nigba toun maa pada de baluwe, iyalenu lo je foun pe Dolapo ti gben
omi oun jade, to si ti n we.
Okunrin Emmanuel naa so pe kii se pe
oun fe e fipa ba Dolapo to ti n fe kawon mejeeji maa fe ara won tele, sugbon
toun ko gba fun nitori toun ti niyawo ati omo meji naa sun, ntiroi pe awon
mejeeji lawon jo wa nile.
Gbogbo oro ti Emmanuel so kale ni
yii ti adajo A. S. Soneye fi pase pe ki Emmanuel san owo itanran egberun lona
ogorun naira pelu oniduro kan to se e fokan tan, sugbon si iyalenu, se ni
Emmanuel so pe oun ko lowo lowo, toun ko si ni eni to maa duro foun.
No comments:
Post a Comment