Oko mi ko gba oyun lowo mi, E tu wa ka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Oko mi ko gba oyun lowo mi, E tu wa ka

Pelu ebe niyale ile kan, Arabinrin Aminat Soyomi fi n soro niwaju ile ejo koko koko to wa ni Ake niluu Abeokuta lojo Tusde ose to koja pe ko tu igbeyawo olodun metala to wa laarin oun ati oko oun Ogbeni Waheed Soyomi ka nitori wahala ojoojumo to n ba oun fa.

Iyale ile naa so pe wahala naa bere nigba toun loyun omo won keji to je omodun mejo, to ni oko oun so pe ko ye koun sare loo loyun le omodun merin, to je pe latigba naa ni ko ti gbo bukata ninu ile mo, to si je pe awon jo n sun, tawon tu jo n ji ninu ile kan naa ni.

Aminat tun so pe se ni ina wahala naa bere ni pereu nigba toun loyun omo keta toun je omodun marun un bayii, nigba ti oko oun so pe oyun ale loun gbe wa sile, nitori to so pe oun ko loun loyun naa.

O ni titi di boun se n soro yi ni oko oun ko mo boun se se ibi omo (placenta) naa, nitori pe ko yoju, ko da a, to je pe funra oun loun se ikomo omo naa.

O nigba to su oun loun gbe e lo si ileese ijoba to n ri oro araalu, iyen Welfare Court tijoba ipinle Ogun to wa ji Oke-Mosan lodun marun un seyin, ko to o di pe won tare awon lo si kootu molebi ti ile ejo giga nibi ti ejo naa wa bayii.

Obinrin naa so pe oun ko fe ki oko oun gba omo lowo oun nitori to so pe oun ko loun ni omo naa, ati pe ko tii ju osu meta lo ti baba awon omo oun sese so pe omo won keji jo oun pupo, eyi to muu san owo ileewe ni taamu odun yii.

Nigba ti Baale ile naa, Waheed Soyomi n ro ejo ti e, o loun ko loro pupo lati so nitori pe ile ejo molebi ti ni koun gba awon omo naa sodo, sugbon tiyawo oun ko fi awon omo naa sile foun, idi ni yii to tun fi wa sile ejo koko koko lati wa a da oju oro ru nibi.

Oloye Akande O. O ranse pe akobi omo won, iyen Alia to je omodun mejila lati beere lowo e pe nibo ni won fe e lo laarin odo iya ati baba won, sugbon pelu iyalenu se lomo naa so pe oun ko fe ipinya laarin awon mejeeji, oun fe kawon jo maa gbe papo pelu alaafia.

Awon onidajo mejeeji, Oloye Akande O. O ati Arabinrin Onarebu Majekodunmi H. I so pe pelu awon iwe to wa niwaju awon, ko siwe to so pe kenikeni ninu won ko omo sodo, ati pe ko si nkan tawon le se lori oro olomo de nitori pe ile ejo giga to ju awon lo ti n gbo ejo naa lo tele.

Won ni ti won ni kawon ya won bi won ba rii pe ko si atunse mo, fun idi eyi, ninwon pada wa lojo keji osu karun un lati wa a gba idajo won, bee ni won ro won pe ki won lo ronu won jinle daadaa lati ma da ona igbesi aye awon omo won ru latile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI