Asiri Christian to n ta kodiini tu o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Asiri Christian to n ta kodiini tu o

Airise se lo je ki n gbe igba e - Christian 


Yoruba bo won ni oruko n ro ni, sugbon se loro naa yi pada fun gendekunrin omo Yibo kan, Christian Ifedebo lose to lo lohun nigba towo olopaa te e pelu paali egbogi oloro ti won n pe ni kodinni (codeine), ti ko din ni metala.

Christain
Ohun ta a gbo ni pe Christian ti won lomo bibi ilu Enugun nipinle Enugun ni lasiri e tu lakoko to n gbe awon oogun naa lo fun okan lara awon onibaara e ti won ni won si n wa ona bi won se maa mu.

A gbo pe Christian lo n ta awon oogun naa fawon eeyan ti won n fa a simu, to si ti so Opolopo awon to odo awon ti won n muu.

Nigba ti Christian n b'AWIKONKO soro, o niyalenu lo je foun nigba tawon olopaa da oun duro pe eru ofin loun ko, toun ko gba ase, sugbon to loun so pe kaadi idanimo wa lara oun tawon olopaa naa ko si faaye sile lati ye kaadi idanimo naa wo.

"Ko tii ju osu merin ti mo ti n sise yi. Imo nipa Physiology/Pharmacology ni mo ka nile eko fasiti ti Nsukka. Odun 2013 ti mo ti se tan ni mi o ti rise se, ti ko si sibi ti mo fe e gba.

"Mo n lo lati gbe awon oja naa lo sodo okan lara awon onibara mi to n je Ogbeni Obi ni, ko to o di pe awon olopaa da mi duro lagbegbe Kara ni Ibafo. Won ko je kin n soro, ati pe gbogbo bi mo se n gbiyanju lati yo kaadi idanimo mi sita lati fi ara mi han won ni won ko gba fun mi.

"Ki tii ju ose meta ti mo mo Ogbeni Obi ni yii, nitori pe o maa n wa ra oja lodo eni ti mo ti n sise ni. Kii se ayederu oja lawon nkan ti won gba lowo mi yi nitori onikaluku awon to n ta iru oogun bayii ni won ni awon to n ba won gba a ta (distributor).

"Nigba ti won koko mu mi, mi o ro pe o le le to gbogbo eyi to n sele yi nitori pe ere ni mo koko pe e. Mo ni kaadi idanimo awon ileese yi lowo, gbogbo nkan ni mo se lati je ki won mo pe emi kii se gbajue tabi okan lara awon janduku."

Agbenuso fawon olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe iro pata gba a ni Christian n pa, ati pe oun n wa ona lati we ara e mo ni, eyi ti ko di awon lowo lati foju e bale ejo lai pe.

Bee lo ni Ahmed Iliyasu to je Komisana won ti pase pe kawon SARS si maa mu lo sogba won lati tubo sewadi e daadaa, ki won le tete mo igbese ti won fe e gbe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI