Asiri awon pasito ge ori eeyan sinu soosi tu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Asiri awon pasito ge ori eeyan sinu soosi tu

Titi di bi e ti n ka iroyin yi loro Tobiloba Ipense to n fise pasito boju lu awon eeyan ni jibiti si n je fawon araalu, paapaa awon to n gbe ladugbo Elebute, Ewekoro nitosi Papalanto nipinle Ogun latari bo se seku pa okan lara awon omo ijo e, Arabinrin Raliatu Ajoke Sanni to ti bimo mefa losu keta to koja yii.

Ese ko gbero ladugbo Elebute lojo Tusde ose to koja yi, nigba tawon agbaagba nipinle Ogun bii Komisana olopaa, Olu-Itori, Olu-Ifo, Oba Owode, awon baale to fi mo Alaaji agba to je egbon Gomina Ibikunle Amosun loo wo iran pasito naa.

Ko si nnkan to n je koro Tobiloba, eni odun mejidinlogoji (38) ti won lomo bibi ilu Ilaje nipinle Ondo naa maa se awon eeyan ni kayeefi bi ko se bi oju e se tutu, to si tun loyaya, iteriba ati irele sawon eeyan, lai mo pe iranse esu paraku ni.

Tobiloba to je oludasile soosi sele ti won poruko e ni Holy Gathering Christian Evangelical Church of God la gbo pe o fe e wonu egbe awo tawon pasito to ba fe e lokiki, to fe maa se awon ayederu ise iyanu fawon eeyan, ki ero repete si le maa wo ninu soosi won wa.

Won ni lojo kokandinlogun osu keta to koja yi ni Tobiloba lo sile iyale ile kan ti ko si nile oko mo, eni to je okan lara awon omo soosi e, Raliatu Ajoke Sanni, eni odun merindinlogoji (36) lati loo ki ni nnkan bi aago mewa ale, ti won si ni won tun ko ibasun fun ara won lai mo pe ise buruku to fe e se wa ninu.

Ohun tawon kan n so ni pe oogun ni Tobiloba fi ba Raliatu sun lale ojo naa, lati ra iye e patapata, nitori ti won so pe se ni Tobiloba ni ki Raliatu lo ra abela (candle) paali kan pelu agbon lati tan an yika inu ile, ko si fi agbon si aarin. Won ni nnkan bi aago meta oru ni Raliatu jade kuro ninu ile lati loo fo agbon naa, sugbon ti ko pada sinu ile naa mo.

AWIKONKO gbo pe Tobiloba koko sebi eni pe oun ko mo nkankan nipa bi Raliatu se rin in, nitori to so pe osu kokanla odun to koja lawon ti foju kan ara won gbeyin. Sugbon nigba ti won bere sii te ninu ti won sib ere sii igbaju bo, se lo sare yi oun pada, to si bere sii ka boroboro pe oun ko loun pa Raliatu, pasito kan to wa ni Iyana Egbado ti won n pe ni Oba Majemu lo pa a fun etutu.

Lara awon araadugbo to gbe iroyin kan siwa leti je ko di mi mo pe iawo Tobiloba maa n sise agbebi, sugbon to je pe opo igba tawon alaboyun ba bimo sibe, ni won maa n wa ibi omo ti, toro a si di isu ata yan-an-yan. A gbo pe bale adugbo naa ti ko ri ba soro ti da si oro naa lai moye igba, ti won si ti kilo fun un pe se ni won maa le e danu kuro ladugbo.

Egbon Raliatu, Dauda Hassan to ni omodun mejidinlogoji (38) loun so pe ojo kejilelogun ni won n wa aburo oun, ti won si ranse pe oun bo ya, oun mo nipa bo se rin in, sugbon toun so pe o see se ko lo ra oja nitori ise aserunloso (hairdresser) lo n se, o si tun n ta oti elerindodo (Pepsi, Coke, Bottle Water) etc ni Wasinmi.

O loun koko ro pe ere ni, sugbon nigba to di ojo keta tawon ko ri, lo je koun ati egbon oun loo foro naa to awon olopaa Itori leti, ti won si bere ise iwadii. Okunrin naa ni okan lara awon omo to n gbe lodo Raliatu, iyen Damilola Joseph to je omo aburo Raliatu to ti salaisi lo je kawon tete ri okodoro oro.

Dauda to ni ise fijilante loun n se so pe gbogbo awon pasito to wa nijoba ibile Ewekoro loun ti loo ba lati beere Raliatu lowo won, sugbon ti won ni won ko rii, ko too di pe Damilola so fawon, tawon si loo gbe nile e.

Damilola Joseph ninu oro ti e so pe “Eemeta ni pasito ti wa sile wa. Lojo ti won maa koko wa si soobu, emi ni mu won lo sile ti momi wa wa. Lale ojo ti won wa yen ni nnkan bi aago mejo ni, ibi ti mo ti n yan gaari nitosi ile ni mo wa ki momi too so fun mi pe ti m ba se tan, ki n wag be ounje mi. Igba ti mo dele ti mi o ri momi, mo wonu ile, mo ri pasito lori beedi pelu sokoto penpe (boxer) nidii, won n nu ara lowo. Bi mo se n jade sita, ni mo pade momi ti won n bo lati baluwe, won beere lowo mi pe ki lo de ti mo fi wonu yara, mo wa a so fun won pe nigba ti mi o ri won. Won ni ki n lo gbe ounje mi nibi tawon gbe e si.

“Emi o sun ile lojo yen, odo dadi won ni mo loo sun. Egbon mi to sun sile so pe nigba toun wonu yara, oun ba ti won tan abela yika, ti momi si jade laago meta oru lati loo fo agbon yen.

Raliatu ti won pa
Nigba toun naa n soro, Sola to je akobi oloogbe so pe “SSS1 ni mo wa ni United Comprehensive High School, Wasinmi. Omodun metadinlogun (17) ni mi. Won jade laarin oru, ko pe ni won tun wole pada. Nigba to di aago meta oru, won tun jade pada, won ni ki n tilekun leyin. Igba to di aago mefa, won pada wa a kan ilekun, emi ni mo lo silekun fun won. Won wa a so fun mi pe ki n toju awon aburo mi daadaa, nitori pe irin ajo tawon n lo yen ma a pe kawon to o de, ki n ma je ki iya je awon aburo mi.

“Mi mo pasito yen ri, sugbon eekan soso ni emi ati momi mi lo si soosi won, iyen lojo kerin osu keji ti won se ajodun. Mo ma n ri won nile wa tele sugbon mi o ri won lojo yen nitori pe mi o si nile. Mo fe e ki ijoba ran emi ati awon aburo mi lowo, nitori pe ko seni to ma maa toju wa bi iya wa. Pasito ti jewo ni tesan pe awon ko lawon ge ori, ati pe oun loun fun won adireesi ile wa, tawon pasito kan fi wa a gbe momi wa.”

Iya Raliatu Arabinrin Olufunmilayo Adebola, eni odun marundinlogorin (75) ati baba e, Hassan Adebola, eni odun mejilelaadorun (92) nigba ti won n soro pelu ibanuje okan so pe iku oro ni won fi pa omo won to fe e je pe oun lo n gbo bukata ebi ju. Bee ni won rawo ebe sijoba pe ki won ma se je kawon to pawon lekun ale lo lai jiya ese won. 

Tobiloba nigba to n soro so pe “Ninu os kokanla odun to koja ni Arabinrin kan, Oluwakemi Isola mu mi lo sodo Daniel Sopeju. Latigba baa ni won ti bere sii da mi laamu pe ki n wa wonu egbe awo won, sugbon mi o gba fun won. Nigba ti won rii pe mi o gba fun won ni won bere sii dunkoko mo mi pe ti mo ba so pe mi o wonu egbe won, awon maa daran si mi lorun, ti mi o si ni le gba ara mi sile.

“Won lojokojo tawon omo ijo mi ba lo sori oke emi, awon a maa pawon leyo kookan. Igba ti wahala naa su mi ni mo beere lowo Oluwakemi pe wo ni maa se wonu egbe naa, oun lo so fun mi pe ki n ko oruko awon omo ijo mi wa, awon lawon maa mu oruko eni to ba wu won leyin tawon ba sewadi.

“Mo wa a ko oruko die lara awon omo ijo mi fun won, ko to o di pe Raliatu ti won n pe ni iya Sola ni won mu. Emi ni mo fun ni adireesi ati bi won se le rii, iyen lojo Wesde ojo kokanlelogun osu to koja. Nigba to di nnkan bi aago mewaa ale ojo naa, ni enikan wa kan ilekun ile mi pea won eeyan n beere mi ninu soosi, mo koko ro pea won ti won wa fun adura ni, sugbon nigba ti mo jade si won, iyalenu lo je Sopeju ati Oluwakemi ni mo ri peluu awon marun un ti won aso pupa ati dudu, mi o da awon to ku mo.

Oku Raliatu
“Mo tun ri iya Sola pelu won, mo wa n beere lowo won pe bawo ni won se de bi pelu iya Sola lai gbe moto wa. Won ni nkan ti agba fi n je eko, abe ewe lo wa. Lesekese ni Sopeju ti mu obe ti kii soju lasan jade, ti won fi okun so enu e ko ma baa pariwo sita, to si ge ori iya Sola, pelu owo e mejeeji.

“Mo beere pe ki ni won fe e fi se ati pe bawo ni won se fe e se eya ara e to ku, won ni lara nkan ti won fi n wo egbe ni. Won gbe ori yen ati apa e mejeeji sinu ikoko funfun, wi pea won maa jo ni. Igba ti won ri bi mo se n gbon, ni won ni ki won mu mi lo sinu ile. Igba ti ile mo, iyawo bi to ri bi mo se n se beere pe ki lo se mi, mo so pe ko si nkankan, mo wa a lo kaakiri ayika soosi naa lati wo ibi ti won ju oku e si, sugbon mi o rii.

“Ojo Sande to tele ni mo sakiyesi ninu ofiisi ti mo n lo ninu soosi naa pe apa pe won wu ile wa nibe, mo wa loo mu (shovel) lati fi wa ile yen, ki n to o ri pe ibe ni sinku naa si, mo si tun loo bu iyepe lati tun fi bo o daadaa.

“Iro ni won pa mo mi pe won ri mi nile iya Sola lale ojo yen, mi o si nibe, looto ni mo ti n lo sile iya Sola, mi o sib a a dore ikoko. Nkan ti won so fun mi ni pe awon ko le lo eni to ba je eje mi. Won ti ni ki n jeje pe mi o gbodo so fenikeni, ati pe se ni mo maa ku, idi ni yii ti mi o fi koko jewo nigba ti won mu mi, nitori mo beru nkan ti won le se fun mi.

“Ko da a, nigba ti a n bo, Daniel n fesun kan mi pe ki lo de ki n to jewo, ati pe ti won ba mu mi, se lo ye ki n da je iya mi ni, wi pe kinni mo fe e ri gba bi won ba pa awa mejeeji.

Daniel ti won tu n pe ni Oba Majemu nigba toun naa n soro so pe iro ponbele ni Tobiloba pa moun, nitpori pe oun ko mon on ri, eekan soso loun rii ri. “Omodun mejilelogoji ni mi, omo Abeokuta ni mi. Kerubu ati Serafu, Oba Majemu niyana Egbado, ni Papalanto si Ewekoro. Mi o si ninu egbe Kankan, nigba ti mo maa koko mo Tobiloba, omo ijo e kan lo muu wa fun mi pe ki n gbadura fun un. Igba ti mo maa tun pada ri leekeji, asiko to fe e se ajodun ninu osu keji odun yi ni, to si fiwe pe mi, mo gbadura fun won, mo si kuro nibe ni temi.

“Igba to ya ti mo tun maa ri ni mo ri pelu awon olopaa ti won ni mo wa ninu egbe okunkun kan, gbogbo igba to n so yi, mo wa lori oke tawon eeyan si wa peluu mi. Emi o mo obinrin yen ri, mi o mo nipa bi won se pa a. emi ko ni mo jo ori e.

Ohun ta a gbo ni pe yato si pe Tobiloba ti won so pe ile eko Methodist High School (Private) to wa ni Arigbajo, n ko eko nipa Isiro, o tun mo nipa eko Oyinbo, Economics, Physics, Chemistry, Biology, Add Maths, bee la tun gbo pe won tun sese gba a gege bi oluko sile eko giga Olabisi Onabanjo to wa ni Ago-Iwoye.

Leyin bii wakati meji ti Komisana olopaa ipinle Ogun Ahmed Iliyasu atawon eeyan to wa lonla gbo pe won sese loo wu oku naa, ti won si tun ri ikoko ti won tinwon gbe ori atawon owo naa si.

Bee la tun gbo pe awon olopaa tun ri awon oogun abenugongo nile Oba Majemu ati nile Tobiloba Ipense, ti won si koko wa ba won logba SARS ti won wa ni Eleweran, iyen ni nnkan bi aago meta aabo osan ojo Wesde.


Lesekese tasiri Tobiloba ti tu lawon olopaa ti lo si soosi e lojo Fraide ose to lo lohun lati daabobo oku naa, ki won ma tun pada wa a wu kuro nibe.

Igba tawon eeyan paapaa awon odo ilu atawon to wa lati ona jin-jin duro titi de Komisana olopaa, ti won ko tete rii ni nkan bi aago mejila lawon odo naa bere sii fehonu han, ti won si bere sii fo ile Tobiloba ati soosi e.

Gbogbo akitiyan awon olopaa lati dawon eeyan lowo ko lo ja si pabo, ko da toro naa tun fe e dija igboro laarin olopaa atawon odo naa, to je pe die lo ku ki won fokuta fo oga olopaa, iyen Area Commander Ota lori, sugbon ti Olorun ko o yo.

Awon odo adugbo naa la gbo pe won dana sun ile Tobiloba Ipense pelu ile kan to wa legbe e, ti won ni okan lara awon omo ijo lo nii. Bee la tun gbo pe awon SARS lo be awon odo naa lati ma dana sun ile iya iyawo Tobiloba to wa legbe e.

Titi di bi e ti n ka iroyin yi la gbo pe Oba Majemu ko tii jewo, sugbon ta a gbo pe oga olopaa SARS, iyen OC SARS dunkoko mo on pe bi ko ba ti jewo, awon yoo wa gbogbo ebi e kan lati lawon run, ayafi to ba jewo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI