Nitori owo: Okwudili sa egbon atiyawo egbon e pa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Nitori owo: Okwudili sa egbon atiyawo egbon e pa

Iyalenu loro gendekunrin kan ti won poruko e ni Okwudili Okoro, ti won lomo bibi ipinle Ebonyi nile Ibo ni si n je fawon eeyan to gbo nipa bo se sa egbon e, atiyawo egbon e pa lose to lo lohun si n je fun won, ko da a, tawon kan tun un gbe e sepe titi dasiko yi.

Okwudili
Ojo Abameta Satide to koja lo lohun la gbo pe Okwudili kuro nile e to wa ladugbo Salon niluu Abeokuta, to si gba ile egbon e to wa ni Ijako lo pelu ore e kan ti won pe ni Kenneth lati loo da won loro.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni ni nnkan bi odun merin seyin ni egbon Okwudili, iyen Azuibike lo si abule won nipinle Ebonyi lati loo muu wa si ipinle Eko, ko ba a le ko nise, koun naa si le deni to n da duro laaye ara e.

A gbo pe ileri ti Azuibike se fun aburo e, Okwudili ni pe to ba farabale ko ise naa, to si mon on daadaa, oun yoo fun lowo ti yoo fi bere okoowo ti e, koun naa si le maa ri owo ti e.

Odun meta gbako la gbo pe Okwudili fi ko ise karakata lodo egbon e, Azuibike to si ti gba aaye. Leyin to gbaaye tan la gbo pe nnkan yi pada fun Azuibike, to je pe se lo n je gbese lawon ibi to ti n ra oja.

Gbogbo bi won se ni Okwudili n da egbon Azuibike laamu pe ko foun lowo toun yoo fi si soobu toun ni won so pe Azuibike ni ko si ni suuru foun, sugbon to so pe iro lo n pa foun, ko fe e foun lowo naa ni.

Won ni losan ojo kan ni Okwudili lo sodo ore e kan to n je Kenneth lati loo foro naa to o leti, tiyen si gba a lamoran pe ko loo hale mo, lai mo pe oro naa yoo buu lowo.

Lojo Satide tisele naa sele, a gbo pe Kenneth lo mu Okwudili lo sibi to ti ra ada tuntun, to si tun lo pon on lodo awon to n pon ada. Ki won to o gba Ijako lo ninnkan bi aago meje irole.

Nigba ti won baa de ile egbon e, asiko ti won n jeun lowo ni. Kani Azuibike mo pe ise ibi ni aburo e fe e wa se, o seese ko ti tetebranse pe.awon araadugbo lati wa gba a sile.

Lojiji la gbo pe Okwudili ati Kenneth bere sii fi ada sa egbon e, atiyawo egbon.e, Jacinta Okoro titi ti won fi ku. Bi won se rii pe awon meejeji ti ku ni won ba ese won soro, sugbon tawon to n gbo ariwo ninu ile tete lo lati loo wo nkan to n sele.

Iyalenu lo je pe nigba ti won maa fi wole, inu agbara eje ni won ti ri Azuibike ati iyawo e, Jacinta, ati pe se la tun gbo pe Okwudili n tu inu ile wo bo ya oun le ri owo toun yoo ko, ko to o di pe awon araadugbo mu.

Lesekese la gbo pe awon eeyan naa ti loo fa a le awon olopaa Ota lowo. Awon olopaa naa la gbo pe won gbe oku toko-taya naa lo si.mosuari Sango.

Nigba yo n jeri oro.naa, Ahmed Iliyasu so pe looto ni, ati pe oun ti tare sodo ajo SARS to wa ni Magbon lati sewadi e daadaa, kimwon si mu Kenneth to salo, ki won le tete foju won bale ejo.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI