Ileejo tu igbeyawo ogun odun ka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Ileejo tu igbeyawo ogun odun ka

Laaro ojo Tosde ose to koja yi ni ile ejo koko koko tu igbeyawo ologun odun to wa laarin iyale ile kan, Arabinrin Abiola Adetunji ati oko e, Ogbeni Kehinde Adetunji ka leyin osu meji ti ejo naa ti dele ejo.

Ohun ta a gbo ni pe iyale ile eni odun mokandinlogoji (39) lo mu ejo oko e lo sile ejo ninu osu keji odun yi naa pe ki won gba oun lowo oko oun to fe e fi oorun igbo pa oun atawon omo meji toun bi fun un sinu ile.

A gbo pe gbara ti Abiola Adetunji ti ro ejo nile ejo lojo kerindinlogun ni awon onidajo meji to n gbo ejo awon eeyan nile ejo naa, iyen Oloye Akande O. O. Ati Onarebu Arabinrin Majekodunmi H. I. ti fise ranse si baale ile naa pe ko yoju sawon lojo kokanlelogun osu keji naa lati wa a so tenu e.

Nigba to di ojo naa la gbo pe Kehinde ko yoju, eyi lo mu ki won tun fise ranse sii pe ko yoju sawon lojo ketala osu keta to koja yi, pe o see se ko je pe iro n iyawo e, Abiola wa a pa mo on nile ejo, ko si tete wa a so tenu e, sugbon ta a tun gbo pe ko yoju.

AWIKONKO gbo nnkan tawon onidajo mejeeji tun so lojo naa ninu iwe ti won tun ko ranse si Kehinde ni pe bi ko ba yoju sawon lojo karun un osu yi, iyen lojo Tosde to koja yi, awon yoo tu igbeyawo naa ka.

Abiola nigba to n fi bibeli bura niwaju awon onidajo mejeeji so pe "Oko mi fe e fi oorun igbo pa emi atawon omo sinu ile, ko si nii toju wa tabi ko fun wa lowo ounje. Emi nikan ni mo n da gbo bukata ninu ile, ti ko tun ni mo fun mi.

"Danfo lo n wa tele, sugbon tirela lo n wa bayii. To ba a ti fe e mu igbo e, se lo maa ti gbogbo ferese ati ilekun, to ma maa fa a bi eni ti aye n se. Ti m ba soro, alupa maku lo maa n fi mi se. Opo igba ni mo ti loo fejo e sun awon ebi e, sugbon ti ko gbo si won lenu ti won ba pe e lati ba a soro.

"Igba to si mi ni mo ko awon omo mi jade kuro nile ta n gbe ni Oke-Ijemo, ti mo si loo gba ile si adugbo Ijaye. Titi di bi mo ti n soro yi, ko tii yoju, tabi ko pe mi lati beere awon omo.

Abiola to ni oti elerindodo ati omi loun n ta tun je ka mo pe omo meji loun bi fun Kehinde, o ni Segun Adetunji to je omodun mokandinlogun (19) ati Oluwasegun Adetunji toun je omodun metadinlogun (17) lawon omo toun bi, ti ko si mo bi won se n lo nileewe.

Oloye Akande nigba tonn gbe idajo kale so pe awon ti gbiyanju gbogbo agbara won lati ma je ki igbeyawo naa daru, sugbon tawon rii pe Kehinde nife iyawo e mo, eyi to fa a ti ko fi yoju lati wa a so tenu.

O loun pa a lase pelu ofin ile ejo koko koko naa pe ki igbeyawo ologun odun naa tuka lesekese. Bee lo so pe tojo tiyawo naa lo lase lati fe enikeni to ba wu won lai si wahala.

Bakan naa lo so pe ki Abiola maa ko awon omo naa si odo e gege bo se n fe, ati pe igba to ba wun baba awon omo naa lo le wa a wo won, ti ko si gbodo ko won pamo fun. O tun pa a lase pe Kehinde ko gbodo de soobu Abiola lati loo fa wahala mo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI