Beeyan ba wa ni Olu ileese olopaa
ipinle Ogun to wa ni Eleweran lojo Tusde to koja yi, to ri bi baba agbalagba
eni ogorin odun (80), Alaaji Abdullah Ayia Bello se n sunkun soro, ko da bi eni
naa ba jori ahun, omije yoo jabo loju onitohun.
![]() |
Lekan ati ore e |
Ohun ta a gbo ni pe, Lekan Enitan to
je okan lara awon araadugbo ti baba naa n gbe ni nomba 194, Agura Road, Kobiti
Abeokuta lo ji moto baba agbalagba to ti feyinti ti pe gbe.
A gbo pe lati ogun odun o le seyin
ni Alaaji Bello ti mu Lekan mora, to si n se e bi omo to bi ninu, ko da a ta a
gbo pe ko si ise ti baba naa kii ran an, nitori to fokan tan.
Odun merin seyin (2014) la gbo pe
baba naa ra moto tuntun, Toyota Camry 1.6 lati maa fi se ese rin leyin ayeye
ojo ibi odun marundinlogorin (75) pelu iranlowo awon omo e, sugbon ko pe la gbo
pe won ji moto naa gbe.
Odun to koja la tun gbo pe awon omo
baba naa tun ra moto Toyota Camry 2.0 ti won n pe ni Big Daddy fun baba won ta
a tun gbo pe inu losu keji odun yi ni won tun ji moto naa gbe.
Lojo ti won maa wa gbe moto naa, se
la gbo pe awon adigunjale naa n pe enikan lori aago lati to won sona bi won se
le ri kokoro moto naa mu, lai mo pe Lekan ni won n pe.
Nigba tasiri maa tu sita, ogba awon
soja niluu Eko lawon kan ti ri moto naa, ti won si lo fi to awon olopaa leti,
ki won to o lo sibe lati loo mu eni to nii, sugbon tiyen so pe ki won se oun
jeje, o lawon to ta a foun.
Eyi lo fa ti okunrin ti won ta moto
naa fun un fi mu awon olopaa lo sile Akeem Aribido pe oun lo ta a foun,
lesekese ti won ri Akeem mu lo ti ni oun lenu to ran oun nise naa, tawon si jo
pin owo e.
Iyalenu lo nigba ti Akeem maa mu
awon olopaa de ile eni naa, odo Lekan Enitan ni, toro naa si di ariwo ladugbo
pe eni to mo ni lo n se ni, tawon araadugbo si bere sii pariwo le e lori.
Akeem nigba to n jewo fawon olopaa
so pe oun ati Lekan lawon jo o ji moto ti baba naa n lo tele lodun 2014, ati pe
Lekan lo pe oun si ise naa, nitori toun ko mo baba naa ri tele.
Baba agbalagba naa, Alaaji Bello to
so pe ojo kefa osu kerin, iyen ojo Satide to koja loun pe ogorin (80) odun
nigba to n b'AWIKONKO soro so pe edun okan lo n je foun pe eni toun mu bi omo,
ti ko sibi ti kii wo ninu ile oun lo tun maa pada gbogun ti oun.
![]() |
Baba agba naa |
Baba naa so awon eeyan ti so foun
nigba ti won ji moto akoko gbe pe ki n mu Lekan daadaa nitori o mo nipa e,
sugbon nitori toun jeri e loun se so pe ko.le iru nkan be e foun, lai mo pe oun
gan an ni igo leyin ogba fawon adigunjale.
"Ojo kokanla sinojo kejila
osunkeji odun yi lawon adigunjale wa a ka emi ati iyawo mi mole. Awon to ran wa
loru ojo naa gbiyanju lati wole sugbon won ko ri ona wole, ki.won to o pe, to
fi di pe o so ona ti won tun le gba wole fun won.
"Won dunkoko lati pa iyawo mi
nigba ti won gba owo lowo, won ni eni to ran awon so pe ki won wa a pa awa
mejeeji ni, sugbon o so pe oun rii pe eeyan daadaa ni mi loun ko se ni pa mi.
"Won ko beere kokoro moto lowo
mi, ori foonu ni won ti n ba ra won soro to si juwe ibi ti mo n fi kokoro moto
mi si. Bi won se ri kokoro yen ni won ti sa jade.
"Awon eeyan ti mo gbe dide ni
won ri moto naa ninunogba awon soja, iyen army cantonment to wa nIkeja. Nkan
tawon olopaa ba rii pe o to ninki won se fun. Mo mo ipa ti mo ti ko nigbesi aye
e, tawon eeyan gan an maa n so pe omo mi ni. O jo mi loju pe oun lonle iru nkan
bayii fun mi."
Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa
nigba to n soro so pe ko ye kawon eeyan maa finu tan ara won ju lasiko yi,
nitori pe omo iya gan an n seku pa ara won.
Bee lo seleri pe lai pe loun yoo
foju awon odaran mejeeji naa bale ejo.
No comments:
Post a Comment