Ayederu Aafa to n lu jibiti dero tesan olopaa - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Ayederu Aafa to n lu jibiti dero tesan olopaa

Pakopako ni Abduljelili Tajudeen ti won ni ko nise meji ju ko maa fi ise aafa lu awon eeyan ni jibiti obitibiti owo lagbegbe Owode Yewa n wo logba olopaa to wa ni Eleweran Abeokuta lojo Tosde ose to koja nigba tawon olopaa n foju e han fawon oniroyin.

Ohun ta a gbo ni pe Jelili lu baba agbalagba kan, Alaaji Bello Kabiru ni jibiti owo ku die ko to milionu kan naira pelu moto jiipu Toyota 4Runner ti nomba idanimo e je EKY 333 EA lati odun to koja.

Won ni se ni Jelili lo ogbon arekereke e lati tan Alaaji Bello Kabiru ni nkan bi odun meji seyin, tiyen si bere sii ko owo fun un pelu awon iran ayederu to so pe oun ri sii.

Ninu osu kerin odun yo koja la gbo pe Jelili tun riran si Alaaji naa pe bo ba fi le gbe moto naa jade, kiku ni yoo ku sinu ijamba moto, yato si to ba gbe e wa foun lati baa se awon akanse adura si, to si tun so pe ko.loo mu egberun lona aadofa (150,000) naira wa bi ko ba fe e ku iku ojiji.

AWIKONKO gbo pe se lokunrin naa sare loo wa owo naa ya kaakiri to fi pe (140,000) naira, sugbon ti won ni Jelili gba a lowo e pe a fi kowo naa pe ki ise too pari, ose to tele la gbo pe okunrin naa tun sese ri egberun mewaa naira lati fi kun un.

Gbogbo bi won se Alaaji naa se fe e so ile Jelili di ile keji e nitori moto e to fe e gba lowo Jelili ni a gbo pe Jelili n dunkoko mo, ti ko.simmo nkan to le se mo.

Losu ta a sese lo tan yi la gbo pe Alaaji naa gbo iru oro bayii lori redio, ti okan lara awon aburo Alaaji ti won jo gbo iroyin naa si gba a nimoran pe ko loo foro naa to awon olopaa leti, ki won le ba a da si.

Eyi la gbo pe o fa tawon olopaa SARS fi loo fagidi gbe e nile e lojo ti won lo o gbe.

Bo tile je pe nkan ti Jelili so nigba to n b'AWIKONKO soro lose to koja ni pe iro ni won pa mo oun pe se loun foogun gba moto naa lowo Alaaji Kabiru bo tile je pe oun loun beere pe kinni yoo fi san oore pada foun, bi ise ba dahun tan, to ni Alaaji naa lo finufedo foun ni moto naa lati femi imoore han lori adura toun gba fun.

Sugbon nigba ti okan lara awon olopaa SARS to loo mu Jelili so pe bi ko ba je wo boro naa se je, a je pe se lo tun n fi kun iya ti yoo je bawon ba pada gbe e de ileese to wa ni Magbon, ti yoo si sewon ju bo se lero lo.

Eyi lo muu sare yi ohun e pada pe oun yoo jewo fun wa, to si so pe Alaaji Bello lo wa a ba oun pe oun nilo iranlowo lori iyawo oun to maa n nisoro to ba fe e bimo, sugbon to loun ko tun fe ki iyawo naa tun fi ise abe bimo nitori to ti wa ninu oyun ti ko si ni pe e bimo.

Jelili ni lojo naa loun so pe ko loo mu egberun kan naira lona mokandinlogorun (1000 naira note in 99 pieces) ati eedegbeta naira lona mokandinlogorun (500 naira note in 99 pieces) wa, wi pe oun yoo dana sun un leyin toun ba pari ise sii tan, ti ko gbodo seni ti yoo na owo naa.

O ni bo tile je pe leyin toun sise naa tan, ise abe ni obinrin naa tun pada fi bimo, bee ni Alaaji Bello ko le se lati ma de odo oun. Ise keji to loun tun se fun Alaaji naa lo mu ko foun ni moto naa pelu (150,000) naira.

O ni oun ri Alaaji ninu ala pe o fi moto naa nijamba nla kan to la emi lo, leyin toun si pari ise naa lo ni Alaaji Bello so pe koun kuku maa gbe moto naa lo. O niyalenu lo je foun nigba tawon SARS wa gbe oun nile pe oun lu jibiti ni. Bee lo so pe nkan ti ko je koun mk nkan toun le se ni pe oun ko se iwe lati yi oruko eni to ni moto naa pada, iyen change of ownership.

Nigba to n soro, Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa so pe awijare ti ko lese nile ni Jelili n wi, ti ko si ni kawon ma foju e bale ejo tawon ba tubo se iwadii e tan lai pe

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI