Oluwa Mi: Iyawo mi kii ba mi foso, mi o fe mo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Oluwa Mi: Iyawo mi kii ba mi foso, mi o fe mo

Pelu ebe ni bale ile kan, Ogbeni Aremu Onikeku fi n soro nile ejo kokokoko to wa ni Ake niluu Abeokuta lai pe yi pe ki ile ejo tu igbeyawo ogun odun to wa laarin oun atiyawo oun, Arabinrin Olubunmi Onikeku nitori pe kii ba oun fo aso, ko si tun ni da ina ounje foun.
Bale ile naa to so pe bo tile je pe ounje niyawo oun to bimo repete foun, sibe ko si ojo kan to dana ounje nile foun ri, to si maa so pe koun wa maa jeun ninu ounje toun n ta, sugbon to so pe ara oun ko gba a mo.
Okunrin naa so pe orisirisi okunrin lo n tele iyawo oun. O tun niyawo oun ti so omo akobi oun to n je Kemi di alagbere, to je pe ko seni ti ko le ba omo naa sun ladugbo, ko da to so pe won ti n pe omo naa ni aja ladugbo.
O nigba to su oun loun mu Kemi akobi oun lodo mama oun lati lo maa gbe nitori itiju, sugbon tomo naa sa kuro nibe pelu ajoso oun atiyawo oun, ti won ko si je koun gbo. Aremu ni eyi tiyawo oun se to tun dun oun ju nib o se ki iya to bi oun mole, to si bere sii lu nigba toun ko si nile, sugbon toun pada de ba won nibi tawon aaraadugbo ti pe le won lori.
Ninu oro iyale ile naa, Arabinrin Olubunmi Onikeku so pe iro to jinna si otito oro ni oko oun n pa nitori pe oun gan an lo n da wahala sile nile, to si tun ti ko gbogbo eru e kuro nile lati lo maa gbe soosi.

Obinrin naa loun ko figba kan na iya oko oun, nitori lojo kan niya oko oun wa a ba oun nile, to si bere sii se epe nlanla foun atawon omo oun, awon araadugbo ni won n ba oun bebe lojo naa pe ki iya agba naa yee sepe mo.

O ni iya agba naa lo gba oun leti, to si tun yi oun mole ninu igbo, ibe ni oko oun ti baa won lojo naa, to si bere sii so pe se loun n na iya oun, to si je pe ori oun niya e wa lojo naa.

Bakan naa lo so pe bo tile je pe oko oun maa n gbo bukata lori awon omo e, sugbon ti kii foun lowo nigba toun ba ti nilo owo, sibe awon iwa igberaga e lo n da ile wa ru pelu bo tun se lo n gbe soosi.

Nigba ti awon onidajo mejeeji, Oloye Akande ati igbakeji e, Onarebu Majekodunmi n beere lowo won pe kinni nkan ti won fe, Ogbeni Aremu so pe oun ko le ba iyawo oun gbe mo, sugbon toun yoo maa gbo bukata lori awon omo oun bii ti tele, sugbon ti obinrin naa so pe iwa oko oun ko ba toun mu mo, bo tile je pe ko sibi toun fe e lo, nitori pe oun ko bimo feni meji.

Awon onidajo mejeeji wa a ro won pe ki won tun loo soro naa ni tubinubi nijokoo molebi, ki won si pada wa lojo ketala osu yi lati gbo esi. Won ni bi ko ba si ayipada rere tawon mejeeji si n fe ko ara won sile, dandan ni kawon ya won pelu ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI