Iyawo mi ti di erujeje sinu ile, mi o fee mo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Iyawo mi ti di erujeje sinu ile, mi o fee mo

Omije yoo fe e le jabo loju eeyan nigba to ba n gbo bi baba agbalagba tojo ori e ti le ni aadorin (70+) odun se n soro nile ejo koko koko laaro ojo Tusde ose to koja yi nigba to n fesun iyawo e kan awon adajo ile ejo naa.

Baba agbalagba naa, Ogbeni Michael Kolawole Amusan to tun je gbajumo niluu Abeokuta lakoko to n soro je ko di mimo pe iyawo meji loun fe, sugbon se ni iyawo keji naa, Arabinrin Monsurat Olaide Amusan fe e ran oun lo sorun aremabo, nitori naa ki ile ejo tete gba oun lowo e.

Ogbeni Michael so pe odun to koja loun ti mu ejo naa wa, sugbon ti adajo to wa nile ejo nigba naa so foun lojo kefa osu kokanla odun to koja pe koun loo ronu si daadaa, ti adajo naa si tun be oun pe koun loo se iwe pe awon yoo yanju oro naa ni tubi-inubi.

O ni kaka ko san lara iya aje, iyen iyawo oun, se lo tun le ju ti tele lo nitori pe bawon se kuro nile ejo lojo naa se ni iyawo oun Monsurat tun loo dena de oun atiyale oun ninu oko to si bere sii lu oun bii eni lu aso adire.

Michael gbe irin nla kan jade lati fi han awon adajo naa pe irin nla ti Monsurat la mo oun leyin orun re e lojo naa, to je pe Olorun ni ko je koun dagbere faye lojo naa, ati pe niwaju awon aburo e, atawon egbon e lo ti huwa naa ti won si n foun ye eleya. Nibe lo so pe oun ti ranse pe baba Monsurat kiyen to sare gbe okada wa lati wa a ba soro.

Baba naa tun so pe igba kan wa tawon lo kootu Isabo, to je pe se ni Monsurat tun pariwo oun sita pe se loun fi akobi omo oun soogun owo, tawon to n koja lo atawon to wa ni kootu lojo naa si fe maa foju eeyan buruku woun, ko to o di pe oun pe omo naa lori aago lati salaye nkan to sele fun in. O nigba tawon eeyan gbo nkan ti omo naa so lo je ki won mo pe oniranu ni Monsurat.

Iyale ile naa, Arabinrin Monsurat so pe iro nla patapata gba a ni oko oun n pa, to si je pe Olorun lo maa ba oun se idajo fun un bo ti to nitori pe odun 1999 loun ti mo nigba tawon pade.

Obinrin naa ni lojo ti won so pe oun lu won, se ni oko oun gbe iyale oun lo sori ile ile toun n ko lowo lati lo maa fi han an to si mu inu bi oun. O ni ara moto loun la irin naa mo kii se oko oun toun bimo marun un fun.

Monsurat ni opo igba loun ti ran awon eeyan lati ba oun be oko oun, sugbon agidi inu e ti poju, nitori ti ko gbo ebe oun. Bee lo ro ile ejo pe ki won ma je ki oko oun ba tawon omo oun je, ko si foun sile ninu ile to ko foun atawon omo tawon n gbe.

Nigba ti adajo, Oloye Akande O. O n beere pe ki ni baba naa n fe, o ni nnkan merin pere loun n toro nile ejo, akoko ni pe ki won ya won patapata (total separation), eekeji ni pe ko gbodo doju ti oun nita gbangba mo, eeketa ni pe ko gbodo je oruko oun mo, eleekerin ni pe ko je ki n maa ri awon omo mi nigba to ba wun mi.

Oloye Akande ninu oro e lo ti so pe oun ko tii ni da ejo naa nitori pe awon mejeeji tun si ni ise lati se, ki baba naa tun lo ro arojinle daadaa, nitori gege bi ipo e laarin ilu. Bee lo sun idajo min in di ojo keji osu karun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI