Oselu De: Atiku Sabewo Si Goodluck Jonathan, Lo Ba Gboriyin Fun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 21, 2018

Oselu De: Atiku Sabewo Si Goodluck Jonathan, Lo Ba Gboriyin Fun

Igbakeji Aare teleri lorileede yi, Atiku Abubakar ti gbosuba kare fun Aare ana lorileede yi, Goodluck Jonathan fun bo se n gbe oselu awaarawa laruge, paapaa eyi to se lakoko idibo odun 2015.


Atiku sapejuwe Jonathan gege bi akikanju eto oselu awaarawa.

Ojo Wesde to koja yi ni Atiku Abubakar soro yi nile Aare ana naa to wa niluu Otuoke, ipinle Bayelsa lakoko to loo sabewo sii.

Nigba to n ranti ipinu akinkanju ti Jonathan se lati gbe opa ase sile fun Aare Muhammadu Buhari lai si faakaja tabi ikunsinu.

O ni ipinu yi gan an lo je ki Jonathan da yato laarin awon oloselu to ku, paapaa awon Aare to ti n je lorileede Naijiria, nitori pe kii se pe se lo fagidi gbe ipo naa sile.

Atiku tun so pe pelu gbogbo afojusun awon araalu lasiko naa pe ko nii gbe ipo naa sile, o ni nnkan ta n so lorileede yi ko ni a o ba maa so kani Jonathan ko gbe ipo naa sile lero.

Bee lo so pe oruko Goodluck Jonathan ko le pare ninu iwe itan Naijiria pelu bo se gba alaafia laaye lasiko tawon eeyan ti ro pe ogun fe e sele.

Be o ba gbagbe, lasiko ti Atiku sabewo si Gomina Ayo dele Fayose tipinle Ekiti lo ti gba egbe oselu APC lamoran pe ki won wo awokose lara Aare ana, Goodluck Jonathan, ki won si gba kadara won bi won ba padanu idibo lodun 2019.

Nigba to n soro, Goodluck Jonathan dupe lowo Atiku Abubakar fun bo se yan Gomina ana nipinle Ogun, Otunba Gbenga Daniel gege bi alakoso ipolongo idibo Aare odun 2019.

O ni kii se asise pe Atiku yan OGD gege bi alakoso nitori pe nigba toun loo gege bi alakoso ipolongo idibo lodun 2015, oun ri awon ipa ati aseyori to ko lakoko idibo naa.

Jonathan so pe o ti le lodun merindinlogun toun ti mo Atiku Abubakar, iyen lakoko toun je igbakeji gomina ipinle Bayelsa nigba ti Waziri Adamawa wa a fife han si fun ajosepo.

Daniel ni tie naa sapejuwe Jonathan gege bi Aare to kawe julo ti orileede Naijiria ti ni, paapaa bo se tii ipo igbakeji gomina de ipo igbakeji Aare ko too di pe o tun di Aare orileede Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI