Okan lara awon to n foju sona lati jade dupo omo ile igbimo asoju-sofin kekere (House of Representatives) niluu Abuja ninu eto idibo to n lona lodun 2019 labe egbe oselu African Democratic Congress (ADC), Onarebu (Enjinia) Samuel Oluwafemi Abiodun Oni ti so pe olodo paraku lopo awon oloselu ta a ni lorileede Naijiria nitori pe nnkan ti won ran won loo se ko ni won n se.
Onarebu Abiodun Oni to ti jade dupo naa leemeji otooto, sugbon ti ko wole, iyen lodun 2011 ati 2015 labe egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP lo soro yi lakoko to n b’AWIKONKO soro lose to koja niluu Abeokuta.
Oni to tun je Onimo-ero, to fe loo soju ekun Obafemi Owode/Odeda so pe owo kan wa ti won maa n pin fawon ekun, eyi ti won n pe ni Constituency Allowance losu meta-meta to je pe se ni won maa n da owo naa sapo ara won, ti won kii fi jise fawon eeyan won ti won fi ran won
si.
Ninu oro e, o je ko di mi mo opo awon to n gba owo naa lo tun je pe bi won ba gba a tan, okada, keke maruwa, ero ilota atawon nnkan min in ti ko se e gbo si eti ni won n ra lati pin fun awon araalu, ti won a si maa so pe awon n ro awon eeyan lagbara.
O bu enu ate lu iru iwa bayii pe ko boju mu to nitori pe se lo dabi eni pe won fe e so awon araalu di onise kan soso, to si je pe orisirisi anfaani lo kun agbegbe wa, ti won le gba lati fi ran awon araalu lowo, bii ki won se awon eto idagbasoke agbegbe, ati bee bee lo.
Bakan naa lo tenumo on pe edun okan lo maa n je foun bawon oloselu min in se maa n gbagbe awon ti won dibo fun won leyin ti won ba wole tan, to si so pe ko ye ko ri be e nitori pe ileri ti won se fawon eeyan lakoko ipolongo idibo kii se nnkan to ye ki won gbagbe lai boju wo eyin mo.
Nigba to n so idi to fi fegbe oselu PDP tawon eeyan mon on mo lati ibere sile loo si egbe oselu SDP, o ni kii se oro to se e fi pamo pe egbe oselu PDP ti ku lorileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun.
O so pe ko seni meji to pa egbe PDP run bi ko se Seneto (Omoba) Buruji Kasamu latari bo se n lo agbara ati owo to ni lati fi pa enu awon to le so otito ninu egbe naa mo, tawon yen naa si di eru owo labe e.
Abiodun Oni so pe ko si egbe toun tun le e gba jade mo, bi ko se egbe tuntun, to ni afojusun rere fawon araalu, ti kii sii se egbe etanje, paapaa bi egbe oselu APC to n se ijoba lowo, bee lo so pe ijoba egbe oselu APC ti su awon araalu, won si n fe egbe ti yoo se ti won.
Nigba to n so ipinu e lati jade dupo naa, Onarebu Oni so pe, ife toun ni sawon eeyan lo mu koun fe e loo soju won niluu Abuja, ki won si le je mudun-mudun eto isejoba awaarawa ti won n pariwo lati odun 2019, to je pe oto ni nnkan tawon eeyan n ri nipa e.
Bakan naa lo so pe eto toun fe e gbe wa fawon eeyan oun boun ba wole lodun 2019 yato patapata si eyi tawon to ti n soju awon eeyan won lati odun 1999. O je ko di mi mo pe asiko taa wa yi ti lu jara, tawon eeyan ko si gbodo sun ki won ko ori won sibi kan naa, ti won si gbodo ba awon egbe won kaakiri agbaye pe.
No comments:
Post a Comment