Bi e se n ka iroyin yi lowo ni gbogbo awon ara Oja-Odan nijoba ibile Yewa North ti n gbaradi lati je anfaani eto ayewo ilera ofe ti Onarebu Oladipupo Adebutu fe e se fun won lojo keedogbon osu yii, iyen ojo Tosde ose to n bo.
Gege bi a se gbo, won ni lara nnkan to je Onarebu Adebutu tawon eeyan tun n pe ni LADO logun ju ni alaafia awon eeyan, to si maa n se iranlowo owo ati itoju to peye fawon to ba ni ailera.
Idi ni yii to fi gbe eto naa kale fawon araalu, ti eyi kii sii se akoko iru e, nitori to ti se e fawon araalu Ijebu kaakiri, to si tun fe e gbe ipolongo naa lo fawon ara a Yewa.
Lara awon aarun tabi aisan ti won fe e ye wo lara awon araalu ni aarun ito suga (Diabetes) ati eje riru (Hypertension) lai gba owo lowo enikeni.
AWIKONKO ti e tun gbo pe LADO setan lati se iranlowo owo fawon to ba ni aarun tabi aisan wonyii lati loo toju ara won nibikibi tabi ko ran won lo sawon osibitu ti won ti n toju awon aarun naa lati loo gba itoju ofe nibe.
No comments:
Post a Comment