KI LE MAA SE, TI E BA GBO PE AYE FE E PARE LAARIN ISEJU MEWAA??? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 21, 2018

KI LE MAA SE, TI E BA GBO PE AYE FE E PARE LAARIN ISEJU MEWAA???

Hmmmmm! Ma a toro idariji ese mi ni o, ti m ba ni anfaani lati sare de soosi, boya ki ipe too dun ni o, tabi ki aye too pare. Ese po lorisirisi ti mo ti se, bii iro pipa, ko seni ti kii jale, o kan le ju ara won lo, maa toro idariji ese igberaga, pansaga ati bee bee lo ni maa bebe pe ki Olorun dariji mi.
- Rukayat Solademi, Abeokuta


Ko si nnkan ti mo fe e se ju wi pe ki n toro idariji ese pe ki Olorun dariji mi fun gbogbo ese ti mo ti se patapata. Awon ese to je pe emi nikan ni mo mo won, ti mi o si le so o sita, paapaa awon ese owo iya mi ti mo ti ji nigba ti mo wa ni kekere. Mo tun se awon ese repete ti mi o ni fe e so o sita, ki Olorun fi aanu e dariji mi.
Smith - Abeokuta


Ko si nnkan ti mo fe e se ti m ba gbo pe aye fe e pare ju pe ki n toro idariji awon ese ti mo ti se bii ojukokoro, agbere atawon ese min in ti bo lasiri. Leyin yen, se ni maa lo sun nitori pe mi o ni fe mo bo se maa ri. O temi lorun ko ba mi loju oorun ju ki n foju rii. Ki Olorun saanu mi, ki n ma jiya laye ati lorun, ko je ki n ri orun rere wo.
Tinuade Adekoya - Sagamu


Kinni in mo tun fe e se ju pe ki n toro idariji ese mi lo. Gege bii musulumi tooto, maa be Olorun pe ko se aforiji fun mi, ko je ki n ri Alujanna e wo, nitori pe nnkan to se pataki, to si se koko ni eeyan ti Olorun da sile aye tun le pada jeere Alujanna. Ki Olorun saanu wa.
Taiwo Kazeem, Abeokuta


Ti m ba koko gbo iroyin naa, maa koko dupe lowo awon obi mi ti won bi mi sile aye, ti won tun toju mi titi ti mo fi dagba debi ti mo de yii. Maa je ki won mo bi inu mi se dun si, maa si tun je ki won mo awon nnkan ti mo n fi pamo fun won lati ojo pipe wa. Leyin yen, maa be Olorun pe ko dari gbogbo ese ti mo ti se patapata, iyen awon ese ti mo nipa e, atawon ese ti mi o mo nipa. Ki Olorun gba wa, ko je ka ri orun rere wo.
Okolie Habibat - Delta


Ibeere nla ni ibeere ti e bere yi o, ti m ba gbo iru nnkan bayii, ni temi o, mi o le so telo min in o, nitori pe a yato si ara wa. Sina, iyen agbere ni maa koko loo fi iseju marun ninu iseju mewaa yen se, leyin e ni maa wa sese loo toro idariji ese mi lowo Olorun. Awon ese bii sina, oti mi mu ati bee bee lo ni maa so pe ki Olorun dariji mi.
Daniel Kehinde - Eko


Ese po repete ti mo se o, ki Olorun dariji mi pelu aanu e. Ti m ba koko gbo pe iseju mewaa pere lo ku ki aye pare, mi o ni nnkan meji ti mo tun fe e se ju pe ki n yi oju si Olorun pe ko dariji ninu awon ese bii agbere atawon ese min in ti mo tun ti se, ki n le ri ijoba orun wo. E seun o.
Oluwatosin Ajoke, Abeokuta

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI