Ile ti mo ko ni oko mi n gbe, mo lee jade - Sherifat - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, July 2, 2018

Ile ti mo ko ni oko mi n gbe, mo lee jade - Sherifat


Beeyan ba ri bi iyaale ile kan, Arabinrin Sherifat Taiwo se n kunle be ile ejo kokokoko to wa ni Ake Abeokuta lojo Tusde ose to koja yi pe ki won ba ou8n tu igbeyawo to wa laarin oun ati oko oun, Hassan Taiwo ka, nitori pe iwa e ko ba toun mu mo rara yoo mo pe ija lo de ti orin d’owe.
Bo tile je pe baale ile naa, Hassan ko yoju si kootu lojo naa, ti Sherifat naa ko si so iye odun toun ati oko ti n ba ife won bo, sugbon oro to n so fi han daju pe iya n dagbe lobinrin naa fe maa se.
Sherifat so pe “Kii se pe bo ya mo fe e lo l’oko min in ni mo se fe e ko oko mi sile, sugbon mi o tii ri iru okunrin bi oko mi ri nitori pe bukata ile ko joo loju, kii bikita si alaafia emi atawon omo mi. e ma je ki n tan yin, emi ni mo ko ile ta a jo n gbe, ti mi o si fin ii lara rara, pelu ife ni mo fi n baa lo po.
“Lojo kan ni oko mi wa a ka mi soobu pelu ore e kan, to si bere sii lu mi mo 'be. O tun loo so fun baba to gbe soobu fun mi pe ko le mi danu ninu soobu naa, ko si gbe e f'elomin in.
“Eyi to tun maa n kan mi lominu ni pe gbogbo awon omo ti mo bi fun un kii gbe seyin mi, eyin baba won ni gbogbo won n wa, o ti e to abikeyin omo mi, kii fe e gbo pe mo soro baba won laid a rara. E saanu mi Oluwa mi, mi o loko mo o.”
Ibi ti Sherifat soro de re ti Oloye Akande O. O to je Aare ile ejo naa ti so pe ko si gbenu e dake naa nitori pe oko e to n fejo e sun ko si ni kootu, nitori naa ko loo fun oko e niwe pe kootu fe e ri lojo kerinla osu ta a wa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI