EYI NI BI IJAMBA MOTO SE PAAYAN DANU L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 22, 2018

EYI NI BI IJAMBA MOTO SE PAAYAN DANU L'OGUN


Ariwo ikunle abiyamo lo gba eni awon ara lagbegbe Owode Ijako lojo Wesde ojo kinni in osu yi nigba ti oko boosi akero kan loo kolu olokada kan, to si te e pa raurau.

Oku kan re e
Gbogbo awon tisele naa soju won ni ko si le gbagbe bisele naa se waye, paapaa bo se je pe olokada naa ti won nibise e lo n lo sagbako iku ojiji yii.

A gbo pe oko akero boosi to ni aawo ilu Eko, iyen Varagon ni won so pe ere asapajude to n ba bo lo fi loo gba olokada naa danu lasiko to fe e de ibi ti gosilo (go-slow) wa.

Won ni lesekese ni awqko naa ti salo, ti ko duro wo oku eni to pa, sugbon to je pe awon eso oju popona tijoba ipinle Ogun ni won pada le e mu, ti won si rii mu lagbegbe Sango, sibe, a gbo pe awako naa tun ri aaye salo.

Awon TRACE la gbo pe won pada gbe oku okunrin naa lo si mosuari osibitu jenera to wa ni Ifo, bee ni won gbe boosi naa lo sinu ogba won.

Ijamba keji la gbo pe lagbegbe Saapade lo ti sele nigba ti won so pe oko ayokele Hyundai ti nomba idanimo e je KJA 256 CK lo so ijanu e nu, to si sare wo abe tirela ti won paaki segbe titi.

Agbenuso fawon osise TRACE, Ogbeni Babatunde Akinbiyi to fidi iaele naa mule je ko di mi mo pe eeyan meta lo wa ninu moto naa, to si je pe eeyan kan soso lo dagbere Faye, nigba tawon mejo to ku farapa yannayanna.

Mosuari osibitu jenere to wa niluu Isara la gbo pe won gbe oku obinrin to ku sonu ijamba naa lo, tawon meji to ku si wa ni yara ti won ti n toju awon to nisele pajawiri, nibi ti won ti n gba itoju.

PÍN-IN KÁÀKIRI