MI O LE FI EGBE OSELU PDP SILE LAILAI - KASAMU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, August 3, 2018

MI O LE FI EGBE OSELU PDP SILE LAILAI - KASAMU

Seneto Buruji Kasamu ti fowo soya pe ko seni to le le oun kuro ninu egbe egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP, ayafi toun ba pinu lati fi egbe naa sile funra oun.


Nitori naa, o so pe ojulowo pombele omo egbe oselu PDP loun, ti mimi kan ko si le ye oun kuro ninu egbe naa.

Kasamu lo soro yi niluu Abeokuta lonii ojo Tosde lasiko to n bawon omo egbe naa soro nibi ipade gbogboogbo egbe naa ti won gbe kale.

O lawon to n gbero lati yo oun kuro ninu egbe naa kan n se ere omode lasan ni, ofo lori ofo si ni peluu, nitori pe iwe ase ti kootu foun nigba ti won pase lati da awon alakoso egbe naa lowo ko lati yoo kuro ninu egbe.

Kasamu wa gba alaga egbe naa lapapo, Uche Secondus lamonran pe ko bowo fun ase kootu, nitori pe ko seni to ba ju ofin lo.

Saaju akoko yi nigba to n soro, alaga egbe oselu PDP, Enjinia Adebayo so pe awon ti won ba n pe ara won ni omo egbe igun keji (factional member) kan n fi akoko ara e sofo lasan ni.

O ni pelu ase tile ejo bu owo lu, oun si ni alaga egbe naa titi di osu kerin odun 2020, ti ko si seni to to be e lati tako o.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI