IDIBO OSUN: ADELEKE TI N BORI O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 23, 2018

IDIBO OSUN: ADELEKE TI N BORI O

Bo tile je pe ajo eleto idibo, iyen INEC si n ka esi idibo lowo bayii, iyen lasiko ta a sakojopo iroyin yi tan, sibe, ohun ta a gbo ni pe ninu awon esi ti ajo naa n ka sita, adije sipo gomina labe egbe oselu PDP, Seneto Ademola Adeleke lo n jawe olubori lowolowo.


Ninu ibo ijoba ibile meedeogun ti won si ri ka tan bayii, Adeleke lo n saaju akegbe e, Alaaji Gboyega Oyetola ti egbe oselu APC.

AWIKONKO gbo pe ibo 126, 475 ni Seneto Adeleke fi n la Alaaji Oyetola nigba toun ni ibo 110,775.


Bi ajo INEC se kede eyi sita lo mu kawon omo egbe oselu PDP ti won n satileyin fun Seneto Adeleke ti bere sii fo fun ayo kaakiri ipinle naa, paapaa awon ti won loo jokoo si ofiisi ajo INEC to wa niluu Osogbo lati mo bi nnkan se n lo, orin 'o tii se o, baba tii se o'.

Esi ibo ijoba ibile Osogbo ati Olorunda lawon eeyan n duro de bayii, nitori bo se je pe awon agbegbe naa ni awon oludibo po si juu.

E ku ojulona.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI