KO SI NNKAN TO LE PIN EGBE OSELU APC NIPINLE OGUN - YETUNDE ONANUGA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, September 20, 2018

KO SI NNKAN TO LE PIN EGBE OSELU APC NIPINLE OGUN - YETUNDE ONANUGA PARIWO SITA

Igbakeji gomina ipinle Ogun, Arabinrin Yetunde Onanuga ti pariwo sita pe ko si nnkan to le pin egbe oselu APC nipinle Ogun tawon je omo egbe e, nitori pe isokan, ifowosowopo ati asoyepo wa laarin awon daadaa.


Yetunde Onanuga lo soro yi nibi ipade awon agbaagba egbe oselu naa, eyi ti won se ninu gbongan kan to wa ni adojuko Presidential Lodge, Ibara losan onii, ipade naa ti won se lati fi mo igbese to kan nigba ti yiyan awon oludije sawon ipo lodun 2019, iyen Consensus Candidates ko so eso rere.

Onanuga to soju oga e, Gomina Ibikunle Amosun dupe lowo awon agbaagba egbe oselu naa ti Oloye Derin Adebiyi je alaga e fun bi won ko se je ki ipinya wonu egbe naa, ati bi ona ti won n gba lati yanju awon aawo to see se ko waye.

"E je ki n koko dupe lowo alaga egbe oselu nla wa, Oloye Derin Adebiyi, omo egbe to n sise (member, working committee) fun ise gidi ti won n se e. Won mo ipinle Ogun gege bi ipinle alaafia, a si ma maa rii pe alaafia naa n joba.

"Ipinu to waye lonii, tawon eeyan fowo si yoo wa ninu akosile wi pe nipinle Ogun wa nibi, nigba ti eto konsensoosi (consensus) ko ti see se, eyi lo je ka fenuko lati se idibo abele ti indirect (indirect primary).

"Inu mi dun pe gbogbo awa ta a wa nibi la fowo sii, 'abi bee ko?', mo fe e dupe lowo gbogbo awon igbimo egbe nipinle yi fun ipinu yii. Eyi yoo si je mu egbe ni ilosiwaju.

"Mo fe e fi da gbogbo yin loju pe ko si nnkan to le pin egbe oselu APC nipinle Ogun, ko si nnkan to le mu ka yapa. Won mo wa si alaseyori to n seto idibo ti ko ni wahala ninu, ti a si je aritokasi. Eyi la si ma maa tele.

"E je ka jade lo sita lati lo kede fun won pe a ti pinu lati seto idibo abele ti indirect fun gbogbo awon adije wa. Nibi ti konsensoosi, consensus ti kuna, indirect la fowo sii."

Lara awon to wa nibi ipade naa ni; Alaaji Tajudeen Bello, Onarebu Ishola Adekumbi, igbakeji alaga egbe naa, Onarebu Yinka Mafe, Onarebu Bolanle Gbeleyi atawon min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI