BABA SALA TI KU O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 8, 2018

BABA SALA TI KU O

Gbajumo osere tiata nni, Oloye Moses Adejumo topo awon eeyan mo si Baba Sala ti jade laye leni odun mokanlelogorin.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi se fidi e mule, ni nnkan bi aago mewa ale ojo Sande to koja yi ni Baba Sala dagbere faye niluu Ilesa leyin opolopo aisan ojo-ogbo to se agba aderinposonu naa.


Ko si bi won se le pa iroyin iku baba naa mo latigba tawon to sunmo on Baba Sala ti gbo, idi ni yii ti Ogbeni Isaac Hastrup to je agbenuso leka iroyin e se fidi oro naa mule pe looto ni, iyen laaro onii.

Be o ba gbagbe ninu osu kejila odun to koja niroyin iku agba aderinposonu naa ti koko jade sita, sugbon ti akobi omo Baba Sala, Dele Adejumo so pe aheso lasan ni, digbi ni baba oun wa, ko si nnkan to se e.

Iroyin to te AWIKONKO lowo je ko ye wa pe mosuari eka osibitu ti Obafemi Awolowo Teaching Hospital, iyen Wesley Guild Hospital to wa niluu Ilesa ni won si gbe oku Baba Sala si titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan.

Bee la tun gbo pe ojo Sande meji seyin ni Baba Sala ti lo si soosi gbeyin, ko da, won loun lo sadura igbeyin fun won lojo naa.

Ekunrere iroyin n bo lai pe. E ku oju lona

PÍN-IN KÁÀKIRI