IDIBO PAMARI: OLOYE EGBE OSELU ACCORD META FEGBE SILE LOJIJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, October 8, 2018

IDIBO PAMARI: OLOYE EGBE OSELU ACCORD META FEGBE SILE LOJIJI

Banire Ojukotimi

Pelu bi nnkan se n lo yii, afaimo kegbe oselu Accord nipinle Ogun ma tuka patapata latari bi won se lawon oloye egbe oselu naa labe alaga won, Elder Isiaka Amusa ti gbabodi fawon omo egbe naa.

Yoo je otito, aheso lasan ni lawon omo egbe oselu naa n koko pe oro kan ti won lo n ti ja rain-rain nile tele lati bii ose meloo kan seyin, sugbon ti okodoro wa a foju han daadaa nibi eto idibo pamari ti won se lojo Fraide ose to koja yi ni oluleese egbe naa to wa ladugbo Ita-Oshin lopopona Abeokuta si Eko.

Bo tile je pe ki eto idibo ti won ni aago mewaa aaro ni won fe e bere naa, sugbon to je pe aago meta koja iseju die osan ni won sese bere lawon omo egbe ti bere sii fimu kun labele pe nnkan to ba gba lawon yoo fun un, paapaa bi won se da won jokoo tenikeni ko si yoju si won lati ba won soro pe ki won ni suuru die.

Ohun tawon kan to soro si AWIKONKO leti n so ni pe nnkan ti yoo ba gba lawon yoo fun lati rii pe eni tawon fe lo wole, tawon min in naa si n so pe afeni ti yoo ba ku lo ku, bi won ko ba fa adije tawon ti mo tipe kale.

Ninu iwadii t'AWIKONKO se la ti gbo pe awon kan ninu awon oloye egbe oselu Accord, ti won ni Elder Amusa, iyen alaga won lewaju ti se ipade pe ki won ma je kawon lo Sir Tope Tokoya tawon omo egbe naa ti mo tele gege bi adije sipo gomina.

A gbo pe won ni bi won ba lo Sir Tokoya gege bi adije, o see se ki won ma rowo mu lodun 2019 latari awon esun kan ti won lawon kan fi kan an, paapaa bi won tun se ni ko lowo lowo daadaa.

Idi ni yii ti won lawon kan fi ranse si Otunba Rotimi Paseda toun ti figba kan ri dije sipo gomina labe egbe oselu UPN lodun 2015 pe ko wa a gbakoso egbe naa.

AWIKONKO gbo pe Paseda ti won loun ko tii mo nnkan to n fe, nigba to de be, se ni won loo fe e dabaru gbogbo eto ati ilana egbe naa, idi ni yii ti won lawon kan ko fi faramo, to si mu ki won le e danu.

Gbogbo akitiyan ti won lawon kan ti won ni won gbabodi fun won n gba lati rii pe Sir Tokoya ko je eni ti won yoo fa kale la gbo pe o ja si pabo, idi ni yii ti won fi panupo pe ki won wa oruko kan gbe jade lati fi tako Tokoya nibi idibo pamari won.

Eyi lo fa a, ti won fi mu oruko enikan ti won pe ni Arabinrin Ibukun Sotubo pe kawon loo fi tako Tokoya. Awon kan to b'AWIKONKO soro je ko ye wa pe won kan fe e lo oruko naa lati fi gbaaye sile fun eni to le na owo fun egbe, ti won yoo si gbe eni naa jade, bi Tokoya ba fidi remi.

Yato si eyi, lara awon to fe e dije sipo asoju-sofin niluu Abuja ati omo ile igbimo asofin nipinle Ogun ko gbeyin ninu awon ti won fi oselu yi han, pelu bi won ni won se gba owo lowo awon kan, ti won si yo oruko awon ti won ti mo tele kuro.

Latigba ti asiri naa ti lu sita la gbo pe awon omo egbe naa ti n fehonu han labele, ta a gbo pe won n duro de ojo idibo abele won lati fo gbogbo e loju, konikaluku won si mo iwon to gbe.

Lati nnkan bi aago mejo aaro la gbo pe alaga won atawon kan ti n se ipade lori bi won se fe e seto idibo abele naa, eyi to fa a ti won ko fi tete bere ipade, ti won si dawon eeyan to wa lati gbogbo ijoba ibile ogun to wa nipinle naa duro, ti won ko si jade sita lati rawo ebe si won lori bi won se dawon duro.

Ohun ta a gbo ni pe, bi won se pari ipade won ni won sare ranse sawon ajo INEC lati maa bo. Lesekese tawon yen naa si de ni won bere. A gbo pe ibinu lawon osise INEC fi kuro nigba ti won rii pe o see se ki wahala be sile pelu bi won se ri bi nnkan se n lo.

Konsensoosi (consensus) la gbo pe won fi dibo yan awon adije sawon ipo to ku yato si ti gomina ti won se ni pamari. Bi idibo naa se n lo lowo la gbo pe lara awon ti kii se omo egbe naa tun dibo, to mu ko fe e da wahala akoko sile, bee la tun gbo pe se ni won tun yo oruko awon kan kuro ninu awon to ye ko dibo.

Gbogbo awon awuruju ti won ni won se lati le je ki Sir Tokoya ma jawe olubori yi lo mu kawon omo egbe naa maa binu, tawon kan si ti leri pe bi Tokoya ko ba wole, se lawon yoo lu awon oloye naa lalubami.

Leyin o reyin ti won pada ka ibo naa tan ni Sir Tokoya ni ibo mokandinlogorin (79), to fi feyin akegbe e Arabinrin Sotubo toun ni ibo metadinlaadota (47) lele.

Awon oloye meta pataki ninu egbe naa la gbo pe won ti kowe fegbe naa sile latari bo se je pe Tokoya lo wole.

Awon oloye naa ni; Oloye Oladeinde to je Senatorial leader, Oloye Nathaniel ti won tun n pe ni Uncle Nat toun wa lati ijoba ibile Ewekoro, ati asoju awon obinrin, iyen Senatorial Women Leader ta a si tun gbo pe awon min in si n gbero lati fegbe naa sile.

PÍN-IN KÁÀKIRI