LIBYA MURA LATI FOJU SUPER EAGLES GBO’LE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 12, 2018

LIBYA MURA LATI FOJU SUPER EAGLES GBO’LE

Bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi ba fi le otito, a je pe a fi ki egbe agba boolu agba lorileede Naijiria, iyen Super Eagles lati tun igbaradi won lati koju egbe agbaboolu orileede Libya ti won fe ba a figagbaga lojo Satide Abameta se, ki omi ma baa teyin wo igbin won lenu.


Ohun ta a gbo ni pe won ti gun awon agbaboolu ile Libya labere ti yoo fun won lagbara lati dojuko egbe agbaboolu Super Eagles nibi idije tani yoo lo fun ife eye ile Afrika (AFCON) todun 2019, iyen Africa Cup of Nations.

Papa isere Godswill Akpabio to wa niluu Uyo, nipinle Akwa Ibom ni ifigagbaga naa yoo ti waye lojo Abameta Satide, iyen ola laago merin irole.

AWIKONKO gbo pe akoni-mon-gba egbe agbaboolu naa, Adil Al-Khamisi lo sagbateru bi won se loo gun awon eeyan naa labere ni ileewosan kan lorileede Tunisia, ta a si gbo pe Ahmad Benali lo koko gba abere naa.

Be o ba gbagbe, orileede Libya ti ni aami ayo merin (4 points) ni guruupu E (Group E) leyin ifigagbaga meji ti won gba.

Ojo Tusde ose to n bo ni Super Eagles yoo tun lo si orileede Tunisia lati loo gba ifigagbakeji keji.

Ninu iroyin min in la gbo pe akoni-mon-on-gba egbe agbaboolu Super Eagles ti orileede Naijiria, Gernot Rohr ti so pe Alex Iwobi ni yoo gba aso Mikel Obi lojo Satide ola nibi ifigagbaga pelu egbe agbaboolu ti orileede Libya fun ti idije koopu ile Afrika todun 2019.

 Titi dasiko ta a sokojopo iroyin yi tan la gbo pe Mikel ko tii gbadun ara e daadaa latari bo se afarapa lorileede Russia, iyen ti idije ife eye agbaye to waye nibe.

PÍN-IN KÁÀKIRI