UBEC GBE OWO NLA SILE FUN IDAGBASOKE ETO EKO LORILEEDE NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 12, 2018

UBEC GBE OWO NLA SILE FUN IDAGBASOKE ETO EKO LORILEEDE NAIJIRIA


Minisita foro eto eko lorileede yi, Malam Adamu Adamu ti so pe ajo to n sagbateru eto eko lorileede yi, Universal Basic Education Commission (UBEC) ti setan lati gbe bilionu 142.58 naira sile fun idagbasoke eto eko orileede yi.

Adamu lo fidi oro yi mule niluu Kaduna lai pe yi nibi ipade ti won se peluu awon Oba alaye, agbaagba ati oloye ile Ahusa fun ti awon akekoo ti won ko ri ileewe lo, eyi ti won pe ni Out-of-School.

Ipade olojo meji naa la gbo pe ileese to n ri soro eto eko lorileede yi, Federal Ministry of Education, Universal Basic Education Commission, National Commission for Mass Education and Sultan Foundation for Peace and Development, in collaboration with United Nations Children’s Fund (UNICEF) sagbateru e.

Adamu ni laarin odun 2016 si asiko yi ni banki agbaye ti gbe milionu $611 sile lati fi ran awon omo ti ko lo sileewe lowo, lati le je kawon naa kopa ninu eto eko orileede yi.

PÍN-IN KÁÀKIRI