E MA DA ISE SILE O - ILE EJO PASE FAWON OSISE NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 2, 2018

E MA DA ISE SILE O - ILE EJO PASE FAWON OSISE NAIJIRIA

Ile ejo giga apapo kan lorileede yii, National Industrial Court of Nigeria ti pase fawon osise orileede yi pe ki won ma se gbiyanju lati da ise alailojo olojo-gbogboro ti won n gbero lati lo lojo kefa osu yi sile.


Aaro oni ni Adajo Sanusi Kado pase naa leyin ti Ogbeni Dayo Apata to gbenuso fún ìjọba apapo gbe ejo naa lo siwaju e.

Kado ni bawon osise ba fi da ise sile, ìpalára nla ni yóò jẹ fún ètò orò ajé orileede yi lẹka iṣẹ ìjọba àti iṣẹ adani kaakiri Naijiria, paapaa eka eto ilera nitori pe opo awon èèyàn tí won ba nilo itoju ni won ko ni lanfaani sì osibitu lati gba itoju.

Bẹ o ba gbagbe, lojo Tusde to koja yi ni apapọ awọn osise orileede yi ti dunkooko mo ijoba Naijiria pe bi won ko ba fi kun owo osu to kere julo ti won n san, eyi to je egberun mejidinlogun naira, ki won sì sọ ọ di egberun lona ogbon naira, se láwọn yóò dá iṣẹ sile.

Sugbon ìpàdé tijoba apapo se ni won ti fẹnuko pe egberun marundinlogbon (25,000) naira láwọn lagbara lati san gege bi owo osu to kere julo ti won n béèrè fún, tawon gomina sì sọ pé egberun mejilelogun ati aabo (22,500) naira láwọn lagbara lati máa san.

Ojo kejo osu yi ni Adajo sun igbejo min ìn síi, tawon osise yóò sì ti da ise sile ko too to asiko naa, iyen bi ijoba ko ba da won lohun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI