LEYIN ODUN MEJI LOGBA EWON, SEUN EGBEGBE TUN FOJU BALE EJO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 5, 2018

LEYIN ODUN MEJI LOGBA EWON, SEUN EGBEGBE TUN FOJU BALE EJO

Bi e se n ka iroyin yi, gbajumo puromota, Ogbeni Olajide Kazeem topo awọn eeyan mo si Seun Egbegbe ti wa nile ejo lati gbo idajo to to síi latari esun jibiti ati gbajue ti won fi kan an.


Bẹ o ba gbagbe, o ti le ni ogun osu ti okunrin gbajumo omo jayejaye Eko, to tun maa n gbe awon olorin laruge , to si tun maa n gbe sinima jade ti wa lahamo awon olopaa bayii.

Esun ti won fi kan an ni pe, o lu awon Hausa kan ti won maa n se owo ile okeere si naira ni jibiti owo repete. Won laarin odun 2015 si 2017 ni Seun Egbegbe fi n hu iwa odaran ohun.

Bo tile je pe ile-ejo ti fun okunrin omo jayejaye yii lanfaani lati maa ti ile wa jejo, sibe awon ohun to ye ko se, ti beeli re yoo fi bo si i, Seun Egbegbe ko ti i ri i ko kale.

Saaju asiko yii ni Onidajo Oguntoyinbo ti ile ejo giga kan l’Ekoo ti ni ki Egbegbe ati enikeji e, ti won jo mu, Oyekan Ayomide, lo wa owo beeli milionu marun-un naira eni kookan wa, bee ni won tun gbodo ni oniduro, eni to je oga agba onipo kerindinlogun (level 16) ninu ise ijoba, ti tohun yoo tun ni ile nla l’Ekoo, to si setan lati ko gbogbo e sile, gege bi iduro fun Seun ati ikeji e.

Ojo kewaa osu keji odun 2017 lo ti wa ni ahamo. Ohun ti ileese olopaa so nile-ejo ni pe, o le ni ogoji ileese ti won ti maa n se owo ile okeere, ti Seun Egbegbe fi ogbon jibiti gba owo lowo won laarin odun 2015 si odun 2017. Awon owo ti won so pe Egbegbe fi ogbon jibi gba ree lowo awon Hausa; owo naira to fe to ogoji milionu naira (N39,098,100), bakan naa ni won lo tun gba awon owo ile okeere yii; egberun lona aadorun-un dola ($90,000) ati egberun mejla abo owo poun ile Geesi.

Esun ti won ka si Seun ati enikeji e lese fe to ogoji, bee lawon mejeeji ti so pe awon ko jebi esun ohun.

Sa o, o le ni ogoji Hausa ti won n se dola ti won so pe awon setan lati jerii tako Seun Egbegbe ati ikeji e nile ejo.

Ojo kewaa osu keta ti igbejo ohun waye , o le ni ogbon eeyan ti won wa jerii tako o, sugbon eto igbejo ohun ko fi bee lo daadaa, nitori pupo ninu awon elerii yii ni won ko le so ede geesi, eyi to mu ile-ejo lo wa ogbufo fun won.

Loni-in ni igbejo mi-in yoo tun waye, gbogbo bo ba se lo, le o maa gbo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI