WON NI OBA AROMOLARAN KO KU O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 5, 2018

WON NI OBA AROMOLARAN KO KU O

Lose to koja yi niroyin aheso kan jade sita pe Oba Owa Obokun tile Ijesa nipinle Osun, Oba Adekunle Aromolaran ti waja, eyi to n se opo awon eeyan ni kayeefi lori iroyin naa.


Ere lawon to gbo nipa iroyin naa, paapaa awon to  sunmo Aafin Owa Obokun koko pe e, afigba tọrọ naa kọja oju ti won fi n wo o.

Sugbon ni bayii, awon sun mọ Oba Owa Obokun ti Ile Ijesa, Oba Adekunle Aromolaran ti so pe ko si ooto ninu aheso kan to n lo kaakiri pe ọba naa ti waja.

AWIKONKO gbo pe kabiyesi naa lo silu London logunjo osu kewa odun yii, o si ti pada de silu Eko lojoo Fraide to koja, koda o ba awon kan soro lorii foonu laaro oni.

Iwadi fi han pe ninu ose yii ni oba naa yoo pada si aafin e nilu Ilesa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI